ORIN DAFIDI 56
56
Adura Igbẹkẹle Ọlọrun
1Ṣàánú mi, Ọlọrun, nítorí pé àwọn eniyan ń lépa mi;
ọ̀tá gbógun tì mí tọ̀sán-tòru.
2Àwọn ọ̀tá ń lépa mi tọ̀sán-tòru,
ọpọlọpọ ní ń bá mi jà tìgbéraga-tìgbéraga.
3Nígbà tí ẹ̀rù bá ń bà mí,
èmi yóo gbẹ́kẹ̀lé ọ.
4Ọlọrun, mo yìn ọ́ fún ọ̀rọ̀ rẹ,
ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé láìbẹ̀rù;
kí ni eniyan ẹlẹ́ran ara lè fi mí ṣe?
5Tọ̀sán-tòru ni wọ́n ń da ọ̀rọ̀ mi rú;
ibi ni gbogbo èrò tí wọn ń gbà sí mi.
6Wọ́n kó ara wọn jọ, wọ́n sápamọ́,
wọ́n ń ṣọ́ ìrìn ẹsẹ̀ mi,
bí wọn ṣé ń dọdẹ ẹ̀mí mi.
7Nítorí náà, san ẹ̀san ẹ̀ṣẹ̀ wọn fún wọn;
ninu ibinu rẹ, Ọlọrun, ré àwọn eniyan yìí lulẹ̀.
8O sá mọ gbogbo ìdààmú mi;
ati bí omijé mi ti pọ̀ tó,
wọ́n ṣá wà ní àkọsílẹ̀ ninu ìwé rẹ.
9A óo lé àwọn ọ̀tá mi pada
ní ọjọ́ tí mo bá ké pè ọ́.
Mo mọ̀ dájú pé Ọlọrun ń bẹ fún mi.
10Ọlọrun, tí mo yin ọ̀rọ̀ rẹ̀,
OLUWA, tí mo yin ọ̀rọ̀ rẹ̀;
11Ọlọrun ni mo gbẹ́kẹ̀lé láìbẹ̀rù.
Kí ni eniyan ẹlẹ́ran ara lè fi mí ṣe?
12Èmi óo san ẹ̀jẹ́ mi fún ọ, Ọlọrun;
n óo sì mú ẹbọ ọpẹ́ wá fún ọ.
13Nítorí pé o ti gba ẹ̀mí mi lọ́wọ́ ikú,
o gbà mí, o kò jẹ́ kí n kọsẹ̀,
kí n lè máa rìn níwájú Ọlọrun
ninu ìmọ́lẹ̀ ìyè.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ORIN DAFIDI 56: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010