ORIN DAFIDI 58
58
Kí Ọlọrun jẹ Ìkà níyà
1Ǹjẹ́ ìpinnu tí ẹ̀ ń ṣe tọ̀nà, ẹ̀yin aláṣẹ? Ǹjẹ́ ẹ̀ ń ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan ní ọ̀nà ẹ̀tọ́?
2Rárá o! Ibi ni ẹ̀ ń fi ọkàn yín rò,
iṣẹ́ burúkú ni ẹ sì ń fi ọwọ́ yín ṣe láyé.
3Láti inú oyún ni àwọn eniyan burúkú ti ṣìnà,
láti ọjọ́ tí a ti bí wọn ni wọ́n tí ń ṣìṣe,
tí wọn ń purọ́.
4Wọ́n ní oró bí oró ejò,
wọ́n dití bíi paramọ́lẹ̀ tí ó di etí ara rẹ̀,
5kí ó má baà gbọ́ ohùn afunfèrè,
tabi ìpè adáhunṣe.
6Kán eyín mọ́ wọn lẹ́nu, Ọlọrun;
OLUWA! Yọ ọ̀gàn àwọn ẹgbọ̀rọ̀ kinniun.
7Jẹ́ kí wọ́n rá, kí wọn ṣàn lọ bí omi;
kí á tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ bíi koríko, kí wọn sì rọ.
8Kí wọn dàbí ìgbín tí a tẹ̀ ní àtẹ̀rẹ́, tí ó domi,
ati bí òkúmọ tí kò fojú kan ìmọ́lẹ̀ ayé rí.
9Lójijì, a ó ké eniyan burúkú lulẹ̀;
ìjì ibinu Ọlọrun yóo sì gbá wọn lọ.#58:9 Ìtumọ̀ ẹsẹ yìí kò dáni lójú ní èdè Heberu.
10Olódodo yóo yọ̀ nígbà tí ẹ̀san bá ń ké,
yóo fi ẹsẹ̀ wọ́ àgbàrá ẹ̀jẹ̀ àwọn eniyan burúkú.
11Àwọn eniyan yóo wí nígbà náà pé,
“Nítòótọ́, èrè ń bẹ fún olódodo;
nítòótọ́, Ọlọrun ń bẹ tí ń ṣe ìdájọ́ ayé.”
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ORIN DAFIDI 58: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010