ORIN DAFIDI 24:7-10

ORIN DAFIDI 24:7-10 YCE

Ẹ ṣí sílẹ̀ gbayau, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn, ẹ wà ní ṣíṣí sílẹ̀, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn ayérayé, kí Ọba ògo lè wọlé. Ta ni Ọba ògo yìí? OLUWA tí ó ní ipá tí ó sì lágbára, OLUWA tí ó lágbára lógun. Ẹ ṣí sílẹ̀ gbayau, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn, ẹ wà ní ṣíṣí sílẹ̀, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn ayérayé, kí Ọba ògo lè wọlé. Ta ni Ọba ògo yìí? OLUWA àwọn ọmọ ogun, òun ni Ọba ògo náà.