O. Daf 24:7-10
O. Daf 24:7-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ gbé orí yín sókè, háà! Ẹ̀yin ọ̀nà; Kí á sì gbe yín sókè, ẹyin ìlẹ̀kùn ayérayé! Kí ọba ògo le è wọlé. Ta ni ọba ògo náà? OLúWA tí ó lágbára tí ó sì le, OLúWA gan an, tí ó lágbára ní ogun. Gbé orí yín sókè, ẹyin ọ̀nà; kí a sì gbé e yín sókè, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn ayérayé, kí Ọba ògo le è wọlé wá. Ta ni Ọba ògo náà? OLúWA àwọn ọmọ-ogun Òun ni Ọba ògo náà. Sela.
O. Daf 24:7-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ gbé ori nyin soke, ẹnyin ẹnu-ọ̀na; ki a si gbé nyin soke, ẹnyin ilẹkun aiyeraiye: ki Ọba ogo ki o wọ̀ inu ile wa. Tali Ọba ogo yi? Oluwa ti o le, ti o si lagbara, Oluwa ti o lagbara li ogun. Ẹ gbé ori nyin soke, ẹnyin ẹnu-ọ̀na; ani ki ẹ gbé wọn soke, ẹnyin ilẹkun aiyeraiye: ki Ọba ogo ki o wọ̀ inu ile wa. Tali Ọba ogo yi? Oluwa awọn ọmọ-ogun; on na li Ọba ogo.
O. Daf 24:7-10 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ ṣí sílẹ̀ gbayau, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn, ẹ wà ní ṣíṣí sílẹ̀, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn ayérayé, kí Ọba ògo lè wọlé. Ta ni Ọba ògo yìí? OLUWA tí ó ní ipá tí ó sì lágbára, OLUWA tí ó lágbára lógun. Ẹ ṣí sílẹ̀ gbayau, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn, ẹ wà ní ṣíṣí sílẹ̀, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn ayérayé, kí Ọba ògo lè wọlé. Ta ni Ọba ògo yìí? OLUWA àwọn ọmọ ogun, òun ni Ọba ògo náà.