ORIN DAFIDI 24

24
Ọba Atóbijù
1OLUWA ló ni ilẹ̀ ati gbogbo ohun tí ó wà
ninu rẹ̀,
òun ló ni ayé, ati gbogbo àwọn tí
ń gbé inú rẹ̀;
2nítorí pé òun ló fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ lórí òkun,
ó sì gbé e kalẹ̀ lórí ìṣàn omi.#1Kọr 10:26
3Ta ló lè gun orí òkè OLUWA lọ?
Ta ló sì lè dúró ninu ibi mímọ́ rẹ̀?
4Ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ mọ́, tí inú rẹ̀ sì funfun,
tí kò gbẹ́kẹ̀lé oriṣa lásánlàsàn,
tí kò sì búra èké.
5Òun ni yóo rí ibukun gbà lọ́dọ̀ OLUWA,
tí yóo sì rí ìdáláre gbà lọ́wọ́ Ọlọrun, Olùgbàlà rẹ̀.
6Irú wọn ni àwọn tí ń wá OLUWA,
àní àwọn tí ń wá ojurere Ọlọrun Jakọbu.#Mat 5:8
7Ẹ ṣí sílẹ̀ gbayau, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn,
ẹ wà ní ṣíṣí sílẹ̀, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn ayérayé,
kí Ọba ògo lè wọlé.
8Ta ni Ọba ògo yìí?
OLUWA tí ó ní ipá tí ó sì lágbára,
OLUWA tí ó lágbára lógun.
9Ẹ ṣí sílẹ̀ gbayau, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn,
ẹ wà ní ṣíṣí sílẹ̀, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn ayérayé,
kí Ọba ògo lè wọlé.
10Ta ni Ọba ògo yìí?
OLUWA àwọn ọmọ ogun,
òun ni Ọba ògo náà.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 24: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀