Òfin OLUWA pé, a máa sọ ọkàn jí; àṣẹ OLUWA dájú, ó ń sọ òpè di ọlọ́gbọ́n. Ìlànà OLUWA tọ́, ó ń mú ọkàn yọ̀, àṣẹ OLUWA péye, a máa lani lójú. Ìbẹ̀rù OLUWA pé, ó wà títí lae, ìdájọ́ OLUWA tọ́, òdodo ni gbogbo wọn. Wọ́n wuni ju wúrà lọ, àní ju ojúlówó wúrà lọ; wọ́n sì dùn ju oyin, àní, wọ́n dùn ju oyin tí ń kán láti inú afárá lọ. Pẹlupẹlu àwọn ni wọ́n ń ki èmi iranṣẹ rẹ, nílọ̀, èrè pupọ sì ń bẹ ninu pípa wọ́n mọ́.
Kà ORIN DAFIDI 19
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ORIN DAFIDI 19:7-11
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò