Pípé ni òfin OLúWA, ó ń yí ọkàn padà. Ẹ̀rí OLúWA dánilójú, ó sọ òpè di ọlọ́gbọ́n. Ìlànà OLúWA tọ̀nà, ó ń fi ayọ̀ fún ọkàn. Àṣẹ OLúWA ni mímọ́, ó ń fi ìmọ́lẹ̀ fún ojú. Ìbẹ̀rù OLúWA mọ́, ó ń faradà títí láéláé. Ìdájọ́ OLúWA dájú òdodo ni gbogbo wọn. Wọn ṣọ̀wọ́n ju wúrà lọ, ju wúrà tí o dára jùlọ, wọ́n dùn ju oyin lọ, àti ju afárá oyin lọ. Nípa wọn ni a ti ṣí ìránṣẹ́ rẹ̀ létí; nípa pípa wọ́n mọ́, èrè púpọ̀ ń bẹ.
Kà Saamu 19
Feti si Saamu 19
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Saamu 19:7-11
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò