O. Daf 19:7-11
O. Daf 19:7-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Pípé ni òfin OLúWA, ó ń yí ọkàn padà. Ẹ̀rí OLúWA dánilójú, ó sọ òpè di ọlọ́gbọ́n. Ìlànà OLúWA tọ̀nà, ó ń fi ayọ̀ fún ọkàn. Àṣẹ OLúWA ni mímọ́, ó ń fi ìmọ́lẹ̀ fún ojú. Ìbẹ̀rù OLúWA mọ́, ó ń faradà títí láéláé. Ìdájọ́ OLúWA dájú òdodo ni gbogbo wọn. Wọn ṣọ̀wọ́n ju wúrà lọ, ju wúrà tí o dára jùlọ, wọ́n dùn ju oyin lọ, àti ju afárá oyin lọ. Nípa wọn ni a ti ṣí ìránṣẹ́ rẹ̀ létí; nípa pípa wọ́n mọ́, èrè púpọ̀ ń bẹ.
O. Daf 19:7-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ofin Oluwa pé, o nyi ọkàn pada: ẹri Oluwa daniloju, o nsọ òpè di ọlọgbọ́n. Ilana Oluwa tọ́, o nmu ọkàn yọ̀: aṣẹ Oluwa ni mimọ́, o nṣe imọlẹ oju. Ẹ̀ru Oluwa mọ́, pipẹ ni titi lai; idajọ Oluwa li otitọ, ododo ni gbogbo wọn. Nwọn jù wura daradara pupọ; nwọn si dùn jù oyin lọ, ati riro afara oyin. Pẹlupẹlu nipa wọn li a ti ṣi iranṣẹ rẹ leti; ati ni pipamọ́ wọn ere pipọ̀ mbẹ.
O. Daf 19:7-11 Yoruba Bible (YCE)
Òfin OLUWA pé, a máa sọ ọkàn jí; àṣẹ OLUWA dájú, ó ń sọ òpè di ọlọ́gbọ́n. Ìlànà OLUWA tọ́, ó ń mú ọkàn yọ̀, àṣẹ OLUWA péye, a máa lani lójú. Ìbẹ̀rù OLUWA pé, ó wà títí lae, ìdájọ́ OLUWA tọ́, òdodo ni gbogbo wọn. Wọ́n wuni ju wúrà lọ, àní ju ojúlówó wúrà lọ; wọ́n sì dùn ju oyin, àní, wọ́n dùn ju oyin tí ń kán láti inú afárá lọ. Pẹlupẹlu àwọn ni wọ́n ń ki èmi iranṣẹ rẹ, nílọ̀, èrè pupọ sì ń bẹ ninu pípa wọ́n mọ́.