ORIN DAFIDI 114:1-8

ORIN DAFIDI 114:1-8 YCE

Nígbà tí Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, tí àwọn ọmọ Jakọbu jáde kúrò láàrin àwọn tí ń sọ èdè àjèjì, Juda di ilé mímọ́ rẹ̀, Israẹli sì di ìjọba rẹ̀. Òkun rí i, ó sá, Jọdani rí i, ó pada sẹ́yìn. Àwọn òkè ńláńlá ń fò bí àgbò, àwọn òkè kéékèèké ń fò bí ọmọ aguntan. Kí ló dé, tí o fi sá, ìwọ òkun? Kí ló ṣẹlẹ̀ tí o fi pada sẹ́yìn, ìwọ Jọdani? Ẹ̀yin òkè ńlá, kí ló dé tí ẹ fi fò bí àgbò? Ẹ̀yin òkè kéékèèké, kí ló ṣẹlẹ̀ tí ẹ fi fò bí ọmọ aguntan? Wárìrì níwájú OLUWA, ìwọ ilẹ̀, wárìrì níwájú Ọlọrun Jakọbu. Ẹni tí ó sọ àpáta di adágún omi, tí ó sì sọ akọ òkúta di orísun omi.