Saamu 114:1-8

Saamu 114:1-8 YCB

Nígbà tí Israẹli jáde ní Ejibiti, ilé Jakọbu láti inú ènìyàn àjèjì èdè Juda wà ní ibi mímọ́, Israẹli wà ní ìjọba. Òkun sì rí i, ó sì wárìrì: Jordani sì padà sẹ́yìn. Àwọn òkè ńlá ń fò bí àgbò àti òkè kéékèèkéé bí ọ̀dọ́-àgùntàn. Kí ni ó ṣe ọ́, ìwọ Òkun, tí ìwọ fi wárìrì? Ìwọ Jordani, tí ìwọ fi padà sẹ́yìn? Ẹ̀yin òkè ńlá kí ló dé ti ẹ fi ń fò bí àgbò, àti ẹ̀yin òkè kéékèèkéé bí ọ̀dọ́-àgùntàn? Wárìrì, ìwọ ilẹ̀, níwájú OLúWA; ní iwájú Ọlọ́run Jakọbu tí ó sọ àpáta di adágún omi, àti òkúta-ìbọn di orísun omi.