O. Daf 114:1-8

O. Daf 114:1-8 YBCV

NIGBATI Israeli jade kuro ni Egipti, ti ara-ile Jakobu kuro ninu àjeji ède enia; Juda di ibi mimọ́ rẹ̀, Israeli di ijọba rẹ̀. Okun ri i, o si sá: Jordani pada sẹhin. Awọn òke nla nfò bi àgbo, ati awọn òke kekèke bi ọdọ-agutan. Kili o ṣe ọ, iwọ okun, ti iwọ fi sá? iwọ Jordani ti iwọ fi pada sẹhin? Ẹnyin òke nla, ti ẹ fi nfò bi àgbo; ati ẹnyin òke kekèke bi ọdọ-agutan? Warìri, iwọ ilẹ, niwaju Oluwa, niwaju Ọlọrun Jakobu. Ẹniti o sọ apata di adagun omi, ati okuta-ibọn di orisun omi.