ORIN DAFIDI 105:12-25

ORIN DAFIDI 105:12-25 YCE

Nígbà tí wọ́n kéré ní iye, tí wọn kò tíì pọ̀ rárá, tí wọn sì jẹ́ àjèjì ní ilẹ̀ náà, tí wọn ń káàkiri láti orílẹ̀-èdè dé orílẹ̀-èdè, láti ìjọba kan dé òmíràn, kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ni wọ́n lára, ó bá àwọn ọba wí nítorí wọn. Ó ní, “Ẹ kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan ẹni àmì òróró mi, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe àwọn wolii mi níbi.” Nígbà kan, ó mú kí ìyàn jà ní ilẹ̀ náà: ó ṣẹ́ ọ̀pá oúnjẹ mọ́ wọn lẹ́nu. Ṣugbọn ó kọ́ rán ọkunrin kan ṣáájú wọn, Josẹfu, ẹni tí a tà lẹ́rú. Wọ́n so ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ mọ́ ọn lẹ́sẹ̀, wọ́n ti ọrùn rẹ̀ bọ irin, títí ìgbà tí ohun tí ó sọ fi ṣẹ, tí OLUWA sì jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ọba ranṣẹ pé kí wọ́n tú u sílẹ̀, aláṣẹ àwọn orílẹ̀-èdè sì dá a sílẹ̀. Ó fi jẹ aláṣẹ ilé rẹ̀, ati alákòóso gbogbo nǹkan ìní rẹ̀; láti máa ṣe olórí àwọn ìjòyè rẹ̀, kí ó sì máa kọ́ àwọn àgbà ìlú ní ìmọ̀. Lẹ́yìn náà, Israẹli dé sí Ijipti, Jakọbu ṣe àtìpó ní ilẹ̀ Hamu. OLUWA mú kí àwọn eniyan rẹ̀ pọ̀ sí i, ó sì mú kí wọ́n lágbára ju àwọn ọ̀tá wọn lọ. Ó yí àwọn ará Ijipti lọ́kàn pada, tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi kórìíra àwọn eniyan rẹ̀, tí wọ́n sì hùwà àrékérekè sí àwọn iranṣẹ rẹ̀.