O. Daf 105:12-25
O. Daf 105:12-25 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí wọ́n kéré ní iye, tí wọn kò tíì pọ̀ rárá, tí wọn sì jẹ́ àjèjì ní ilẹ̀ náà, tí wọn ń káàkiri láti orílẹ̀-èdè dé orílẹ̀-èdè, láti ìjọba kan dé òmíràn, kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ni wọ́n lára, ó bá àwọn ọba wí nítorí wọn. Ó ní, “Ẹ kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan ẹni àmì òróró mi, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe àwọn wolii mi níbi.” Nígbà kan, ó mú kí ìyàn jà ní ilẹ̀ náà: ó ṣẹ́ ọ̀pá oúnjẹ mọ́ wọn lẹ́nu. Ṣugbọn ó kọ́ rán ọkunrin kan ṣáájú wọn, Josẹfu, ẹni tí a tà lẹ́rú. Wọ́n so ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ mọ́ ọn lẹ́sẹ̀, wọ́n ti ọrùn rẹ̀ bọ irin, títí ìgbà tí ohun tí ó sọ fi ṣẹ, tí OLUWA sì jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ọba ranṣẹ pé kí wọ́n tú u sílẹ̀, aláṣẹ àwọn orílẹ̀-èdè sì dá a sílẹ̀. Ó fi jẹ aláṣẹ ilé rẹ̀, ati alákòóso gbogbo nǹkan ìní rẹ̀; láti máa ṣe olórí àwọn ìjòyè rẹ̀, kí ó sì máa kọ́ àwọn àgbà ìlú ní ìmọ̀. Lẹ́yìn náà, Israẹli dé sí Ijipti, Jakọbu ṣe àtìpó ní ilẹ̀ Hamu. OLUWA mú kí àwọn eniyan rẹ̀ pọ̀ sí i, ó sì mú kí wọ́n lágbára ju àwọn ọ̀tá wọn lọ. Ó yí àwọn ará Ijipti lọ́kàn pada, tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi kórìíra àwọn eniyan rẹ̀, tí wọ́n sì hùwà àrékérekè sí àwọn iranṣẹ rẹ̀.
O. Daf 105:12-25 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati o ṣe pe kiun ni nwọn wà ni iye; nitõtọ, diẹ kiun, nwọn si ṣe alejo ninu rẹ̀. Nigbati nwọn nlọ lati orilẹ-ède de orilẹ-ède, lati ijọba kan de ọdọ awọn enia miran; On kò jẹ ki ẹnikẹni ki o ṣe wọn ni iwọsi: Nitõtọ, o ba awọn ọba wi nitori wọn; Pe, Ẹ máṣe fi ọwọ kan ẹni-ororo mi ki ẹ má si ṣe awọn woli mi ni ibi, Pẹlupẹlu o pè ìyan wá si ilẹ na: o ṣẹ́ gbogbo ọpá onjẹ. O rán ọkunrin kan lọ siwaju wọn; ani Josefu ti a tà li ẹrú: Ẹsẹ ẹniti nwọn fi ṣẹkẹṣẹkẹ pa lara: a dè e ninu irin: Titi igba ti ọ̀rọ rẹ̀ de: ọ̀rọ Oluwa dan a wò. Ọba ranṣẹ, nwọn si tú u silẹ; ani ijoye awọn enia, o si jọwọ rẹ̀ lọwọ lọ. O fi jẹ oluwa ile rẹ̀, ati ijoye gbogbo ini rẹ̀. Lati ma ṣe akoso awọn ọmọ-alade rẹ̀ nipa ifẹ rẹ̀; ati lati ma kọ́ awọn igbimọ rẹ̀ li ọgbọ́n. Israeli si wá si Egipti pẹlu; Jakobu si ṣe atipo ni ilẹ Hamu. O si mu awọn enia rẹ̀ bi si i pipọ̀-pipọ̀; o si mu wọn lagbara jù awọn ọta wọn lọ. O yi wọn li aiya pada lati korira awọn enia rẹ̀, lati ṣe arekereke si awọn iranṣẹ rẹ̀.
O. Daf 105:12-25 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí wọ́n kéré ní iye, tí wọn kò tíì pọ̀ rárá, tí wọn sì jẹ́ àjèjì ní ilẹ̀ náà, tí wọn ń káàkiri láti orílẹ̀-èdè dé orílẹ̀-èdè, láti ìjọba kan dé òmíràn, kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ni wọ́n lára, ó bá àwọn ọba wí nítorí wọn. Ó ní, “Ẹ kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan ẹni àmì òróró mi, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe àwọn wolii mi níbi.” Nígbà kan, ó mú kí ìyàn jà ní ilẹ̀ náà: ó ṣẹ́ ọ̀pá oúnjẹ mọ́ wọn lẹ́nu. Ṣugbọn ó kọ́ rán ọkunrin kan ṣáájú wọn, Josẹfu, ẹni tí a tà lẹ́rú. Wọ́n so ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ mọ́ ọn lẹ́sẹ̀, wọ́n ti ọrùn rẹ̀ bọ irin, títí ìgbà tí ohun tí ó sọ fi ṣẹ, tí OLUWA sì jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ọba ranṣẹ pé kí wọ́n tú u sílẹ̀, aláṣẹ àwọn orílẹ̀-èdè sì dá a sílẹ̀. Ó fi jẹ aláṣẹ ilé rẹ̀, ati alákòóso gbogbo nǹkan ìní rẹ̀; láti máa ṣe olórí àwọn ìjòyè rẹ̀, kí ó sì máa kọ́ àwọn àgbà ìlú ní ìmọ̀. Lẹ́yìn náà, Israẹli dé sí Ijipti, Jakọbu ṣe àtìpó ní ilẹ̀ Hamu. OLUWA mú kí àwọn eniyan rẹ̀ pọ̀ sí i, ó sì mú kí wọ́n lágbára ju àwọn ọ̀tá wọn lọ. Ó yí àwọn ará Ijipti lọ́kàn pada, tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi kórìíra àwọn eniyan rẹ̀, tí wọ́n sì hùwà àrékérekè sí àwọn iranṣẹ rẹ̀.
O. Daf 105:12-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí wọn kéré níye, wọ́n kéré jọjọ, àti àwọn àjèjì níbẹ̀ wọ́n rìn kiri láti orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè, láti ìjọba kan sí èkejì. Kò gba ẹnikẹ́ni láààyè láti pọ́n wọn lójú; ó fi ọba bú nítorí tiwọn: “Má ṣe fọwọ́ kan ẹni ààmì òróró mi, má sì ṣe wòlíì mi níbi.” Ó pe ìyàn sórí ilẹ̀ náà ó sì pa gbogbo ìpèsè oúnjẹ wọn run; Ó sì rán ọkùnrin kan síwájú wọn Josẹfu tí a tà gẹ́gẹ́ bí ẹrú. Wọn fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ bọ ẹsẹ̀ rẹ̀ a gbé ọrùn rẹ̀ sínú irin Títí ọ̀rọ̀ tí ó sọtẹ́lẹ̀ fi ṣẹ títí ọ̀rọ̀ OLúWA fi dá a láre. Ọba ránṣẹ́ lọ tú u sílẹ̀ àwọn aláṣẹ ènìyàn tú u sílẹ̀ Ó fi jẹ olúwa lórí ilẹ̀ rẹ̀ aláṣẹ lórí ohun gbogbo tí ó ní, Gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀, kí ó máa ṣe àkóso àwọn ọmọ-aládé kí ó sì kọ́ àwọn àgbàgbà rẹ̀ ní ọgbọ́n. Israẹli wá sí Ejibiti; Jakọbu sì ṣe àtìpó ní ilé Hamu. OLúWA, sì mú àwọn ọmọ rẹ̀ bí sí i ó sì mú wọn lágbára jù àwọn ọ̀tá wọn lọ Ó yí wọn lọ́kàn padà láti kórìíra àwọn ènìyàn láti ṣe àrékérekè sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.