ORIN DAFIDI 105

105
Ọlọrun ati Àwọn Eniyan Rẹ̀
(1Kron 16:8-22)
1Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, ẹ pe orúkọ rẹ̀,
ẹ fi iṣẹ́ rẹ̀ hàn ní gbogbo orílẹ̀-èdè.
2Ẹ kọrin sí i, ẹ kọ orin ìyìn sí i,
ẹ sọ nípa gbogbo iṣẹ́ ribiribi rẹ̀.
3Ẹ máa fi orúkọ mímọ́ rẹ̀ yangàn,
kí ọkàn àwọn tí ń wá OLUWA ó máa yọ̀.
4Ẹ wá ojurere OLUWA ati agbára rẹ̀,
ẹ máa wá ojurere rẹ̀ nígbà gbogbo.
5Ẹ ranti iṣẹ́ ribiribi tí ó ti ṣe,
ẹ ranti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ati ìdájọ́ rẹ̀.
6Ẹ̀yin ọmọ Abrahamu, iranṣẹ rẹ̀,
ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, àyànfẹ́ rẹ̀.
7OLUWA ni Ọlọrun wa,
ìdájọ́ rẹ̀ kárí gbogbo ayé.
8Títí lae ni ó ń ranti majẹmu rẹ̀,
ó ranti àṣẹ tí ó pa fún ẹgbẹẹgbẹrun ìran,
9majẹmu tí ó bá Abrahamu dá,
ìlérí tí ó fi ìbúra ṣe fún Isaaki,#(a) Jẹn 12:7; 17:8 (b) Jẹn 26:3
10tí ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ fún Jakọbu gẹ́gẹ́ bí òfin,
àní fún Israẹli gẹ́gẹ́ bíi majẹmu ayérayé,
11ó ní: “Ẹ̀yin ni n óo fi ilẹ̀ Kenaani fún,
yóo jẹ́ ìpín yín tí ẹ óo jogún.”#Jẹn 28:13
12Nígbà tí wọ́n kéré ní iye,
tí wọn kò tíì pọ̀ rárá, tí wọn sì jẹ́ àjèjì ní ilẹ̀ náà,
13tí wọn ń káàkiri láti orílẹ̀-èdè dé orílẹ̀-èdè,
láti ìjọba kan dé òmíràn,
14kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ni wọ́n lára,
ó bá àwọn ọba wí nítorí wọn.
15Ó ní, “Ẹ kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan ẹni àmì
òróró mi,
ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe àwọn wolii mi níbi.”#Jẹn 20:3-7
16Nígbà kan, ó mú kí ìyàn jà ní ilẹ̀ náà:
ó ṣẹ́ ọ̀pá oúnjẹ mọ́ wọn lẹ́nu.#Jẹn 41:53-57
17Ṣugbọn ó kọ́ rán ọkunrin kan ṣáájú wọn,
Josẹfu, ẹni tí a tà lẹ́rú.#Jẹn 37:28; 45:5
18Wọ́n so ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ mọ́ ọn lẹ́sẹ̀,
wọ́n ti ọrùn rẹ̀ bọ irin,
19títí ìgbà tí ohun tí ó sọ fi ṣẹ,
tí OLUWA sì jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀.#Jẹn 39:20–40:23
20Ọba ranṣẹ pé kí wọ́n tú u sílẹ̀,
aláṣẹ àwọn orílẹ̀-èdè sì dá a sílẹ̀.#Jẹn 41:14
21Ó fi jẹ aláṣẹ ilé rẹ̀,
ati alákòóso gbogbo nǹkan ìní rẹ̀;#Jẹn 41:39-41
22láti máa ṣe olórí àwọn ìjòyè rẹ̀,
kí ó sì máa kọ́ àwọn àgbà ìlú ní ìmọ̀.
23Lẹ́yìn náà, Israẹli dé sí Ijipti,
Jakọbu ṣe àtìpó ní ilẹ̀ Hamu.#(a) Jẹn 46:6 (b) Jẹn 47:11
24OLUWA mú kí àwọn eniyan rẹ̀ pọ̀ sí i,
ó sì mú kí wọ́n lágbára ju àwọn ọ̀tá wọn lọ.
25Ó yí àwọn ará Ijipti lọ́kàn pada,
tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi kórìíra àwọn eniyan rẹ̀,
tí wọ́n sì hùwà àrékérekè sí àwọn iranṣẹ rẹ̀.#Eks 1:7-14
26Ó rán Mose, iranṣẹ rẹ̀,
ati Aaroni, ẹni tí ó yàn.
27Wọ́n ṣe iṣẹ́ àmì rẹ̀ ní ilẹ̀#105:27 Ó ṣeéṣe kí ó jẹ́ ní Ijipti. náà,
wọ́n sì ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ní ilẹ̀ Hamu,
28Ọlọrun rán òkùnkùn, ilẹ̀ sì ṣú,
ṣugbọn wọ́n ṣe oríkunkun sí ọ̀rọ̀ rẹ̀.
29Ó sọ omi wọn di ẹ̀jẹ̀,
ó sì mú kí ẹja wọn kú.
30Ọ̀pọ̀lọ́ ń tú jáde ní ilẹ̀ wọn,
títí kan ìyẹ̀wù àwọn ọba wọn.
31Ọlọrun sọ̀rọ̀, eṣinṣin sì rọ́ dé,
iná aṣọ sì bo gbogbo ilẹ̀ wọn.
32Ó rọ̀jò yìnyín lé wọn lórí,
mànàmáná sì ń kọ káàkiri ilẹ̀ wọn.
33Ó kọlu àjàrà ati igi ọ̀pọ̀tọ́ wọn,
ó sì wó àwọn igi ilẹ̀ wọn.
34Ó sọ̀rọ̀, àwọn eṣú sì rọ́ dé,
ati àwọn tata tí kò lóǹkà;
35wọ́n jẹ gbogbo ewé tí ó wà ní ilẹ̀ wọn,
ati gbogbo èso ilẹ̀ náà.
36Ó kọlu gbogbo àkọ́bí ilẹ̀ wọn,
àní, gbogbo àrẹ̀mọ ilẹ̀ wọn.#Eks 3:1–4:17 #Eks 10:21-23 #Eks 7:17-21 #Eks 8:1-6 #(a) Eks 8:20-24 (b) Eks 8:16-17 #Eks 9:22-25 #Eks 10:12-15 #Eks 12:29
37Lẹ́yìn náà, ó mú àwọn ọmọ Israẹli jáde,
tàwọn ti fadaka ati wúrà,
kò sì sí ẹnikẹ́ni ninu ẹ̀yà kankan tí ó ṣe àìlera.
38Inú àwọn ará Ijipti dùn nígbà tí wọ́n jáde,
nítorí ẹ̀rù àwọn ọmọ Israẹli ń bà wọ́n.#Eks 12:33-36
39OLUWA ta ìkùukùu bò wọ́n,
ó sì pèsè iná láti tan ìmọ́lẹ̀ fún wọn lóru.#Eks 13:21-22
40Wọ́n bèèrè ẹran, ó fún wọn ní àparò,
ó sì pèsè oúnjẹ àjẹtẹ́rùn fún wọn láti ọ̀run.#Eks 16:2-15
41Ó la àpáta, omi tú jáde,
ó sì ṣàn ninu aṣálẹ̀ bí odò.#Eks 17:1-7; Nọm 20:2-13
42Nítorí pé ó ranti ìlérí mímọ́ rẹ̀,
ati Abrahamu, iranṣẹ rẹ̀.
43Ó fi ayọ̀ kó àwọn eniyan rẹ̀ jáde,
ó kó àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ jáde pẹlu orin.
44Ó fún wọn ní ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn,
wọ́n sì jogún èrè iṣẹ́ àwọn eniyan náà.#Joṣ 11:16-23
45Kí wọ́n lè máa mú àṣẹ rẹ̀ ṣẹ,
kí wọ́n sì máa pa òfin rẹ̀ mọ́.
Ẹ yin OLUWA!

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 105: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀