O. Daf 105:12-25

O. Daf 105:12-25 YBCV

Nigbati o ṣe pe kiun ni nwọn wà ni iye; nitõtọ, diẹ kiun, nwọn si ṣe alejo ninu rẹ̀. Nigbati nwọn nlọ lati orilẹ-ède de orilẹ-ède, lati ijọba kan de ọdọ awọn enia miran; On kò jẹ ki ẹnikẹni ki o ṣe wọn ni iwọsi: Nitõtọ, o ba awọn ọba wi nitori wọn; Pe, Ẹ máṣe fi ọwọ kan ẹni-ororo mi ki ẹ má si ṣe awọn woli mi ni ibi, Pẹlupẹlu o pè ìyan wá si ilẹ na: o ṣẹ́ gbogbo ọpá onjẹ. O rán ọkunrin kan lọ siwaju wọn; ani Josefu ti a tà li ẹrú: Ẹsẹ ẹniti nwọn fi ṣẹkẹṣẹkẹ pa lara: a dè e ninu irin: Titi igba ti ọ̀rọ rẹ̀ de: ọ̀rọ Oluwa dan a wò. Ọba ranṣẹ, nwọn si tú u silẹ; ani ijoye awọn enia, o si jọwọ rẹ̀ lọwọ lọ. O fi jẹ oluwa ile rẹ̀, ati ijoye gbogbo ini rẹ̀. Lati ma ṣe akoso awọn ọmọ-alade rẹ̀ nipa ifẹ rẹ̀; ati lati ma kọ́ awọn igbimọ rẹ̀ li ọgbọ́n. Israeli si wá si Egipti pẹlu; Jakobu si ṣe atipo ni ilẹ Hamu. O si mu awọn enia rẹ̀ bi si i pipọ̀-pipọ̀; o si mu wọn lagbara jù awọn ọta wọn lọ. O yi wọn li aiya pada lati korira awọn enia rẹ̀, lati ṣe arekereke si awọn iranṣẹ rẹ̀.