Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, ẹ pe orúkọ rẹ̀,
ẹ fi iṣẹ́ rẹ̀ hàn ní gbogbo orílẹ̀-èdè.
Ẹ kọrin sí i, ẹ kọ orin ìyìn sí i,
ẹ sọ nípa gbogbo iṣẹ́ ribiribi rẹ̀.
Ẹ máa fi orúkọ mímọ́ rẹ̀ yangàn,
kí ọkàn àwọn tí ń wá OLUWA ó máa yọ̀.
Ẹ wá ojurere OLUWA ati agbára rẹ̀,
ẹ máa wá ojurere rẹ̀ nígbà gbogbo.
Ẹ ranti iṣẹ́ ribiribi tí ó ti ṣe,
ẹ ranti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ati ìdájọ́ rẹ̀.
Ẹ̀yin ọmọ Abrahamu, iranṣẹ rẹ̀,
ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, àyànfẹ́ rẹ̀.
OLUWA ni Ọlọrun wa,
ìdájọ́ rẹ̀ kárí gbogbo ayé.
Títí lae ni ó ń ranti majẹmu rẹ̀,
ó ranti àṣẹ tí ó pa fún ẹgbẹẹgbẹrun ìran,
majẹmu tí ó bá Abrahamu dá,
ìlérí tí ó fi ìbúra ṣe fún Isaaki,
tí ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ fún Jakọbu gẹ́gẹ́ bí òfin,
àní fún Israẹli gẹ́gẹ́ bíi majẹmu ayérayé,
ó ní: “Ẹ̀yin ni n óo fi ilẹ̀ Kenaani fún,
yóo jẹ́ ìpín yín tí ẹ óo jogún.”
Nígbà tí wọ́n kéré ní iye,
tí wọn kò tíì pọ̀ rárá, tí wọn sì jẹ́ àjèjì ní ilẹ̀ náà,
tí wọn ń káàkiri láti orílẹ̀-èdè dé orílẹ̀-èdè,
láti ìjọba kan dé òmíràn,
kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ni wọ́n lára,
ó bá àwọn ọba wí nítorí wọn.
Ó ní, “Ẹ kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan ẹni àmì
òróró mi,
ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe àwọn wolii mi níbi.”