O. Daf 105:1-15
O. Daf 105:1-15 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa? ẹ pè orukọ rẹ̀: ẹ fi iṣẹ rẹ̀ hàn ninu awọn enia. Ẹ kọrin si i, ẹ kọ orin mimọ́ si i: ẹ ma sọ̀rọ iṣẹ iyanu rẹ̀ gbogbo. Ẹ ma ṣogo li orukọ rẹ̀ mimọ́; jẹ ki aiya awọn ti nwá Oluwa ki o yọ̀. Ẹ ma wá Oluwa ati ipá rẹ̀: ẹ ma wá oju rẹ̀ nigbagbogbo. Ẹ ma ranti iṣẹ iyanu rẹ̀ ti o ti ṣe; iṣẹ àmi rẹ̀ ati idajọ ẹnu rẹ̀; Ẹnyin iru-ọmọ Abrahamu iranṣẹ rẹ̀, ẹnyin ọmọ Jakobu, ayanfẹ rẹ̀. Oluwa, on li Ọlọrun wa: idajọ rẹ̀ mbẹ ni gbogbo aiye. O ti ranti majẹmu rẹ̀ lailai, ọ̀rọ ti o ti pa li aṣẹ fun ẹgbẹrun iran. Majẹmu ti o ba Abrahamu dá, ati ibura rẹ̀ fun Isaaki; O si gbé eyi na kalẹ li ofin fun Jakobu, ati fun Israeli ni majẹmu aiyeraiye. Pe, iwọ li emi o fi ilẹ Kenaani fun, ipin ilẹ-ini nyin. Nigbati o ṣe pe kiun ni nwọn wà ni iye; nitõtọ, diẹ kiun, nwọn si ṣe alejo ninu rẹ̀. Nigbati nwọn nlọ lati orilẹ-ède de orilẹ-ède, lati ijọba kan de ọdọ awọn enia miran; On kò jẹ ki ẹnikẹni ki o ṣe wọn ni iwọsi: Nitõtọ, o ba awọn ọba wi nitori wọn; Pe, Ẹ máṣe fi ọwọ kan ẹni-ororo mi ki ẹ má si ṣe awọn woli mi ni ibi
O. Daf 105:1-15 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, ẹ pe orúkọ rẹ̀, ẹ fi iṣẹ́ rẹ̀ hàn ní gbogbo orílẹ̀-èdè. Ẹ kọrin sí i, ẹ kọ orin ìyìn sí i, ẹ sọ nípa gbogbo iṣẹ́ ribiribi rẹ̀. Ẹ máa fi orúkọ mímọ́ rẹ̀ yangàn, kí ọkàn àwọn tí ń wá OLUWA ó máa yọ̀. Ẹ wá ojurere OLUWA ati agbára rẹ̀, ẹ máa wá ojurere rẹ̀ nígbà gbogbo. Ẹ ranti iṣẹ́ ribiribi tí ó ti ṣe, ẹ ranti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ati ìdájọ́ rẹ̀. Ẹ̀yin ọmọ Abrahamu, iranṣẹ rẹ̀, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, àyànfẹ́ rẹ̀. OLUWA ni Ọlọrun wa, ìdájọ́ rẹ̀ kárí gbogbo ayé. Títí lae ni ó ń ranti majẹmu rẹ̀, ó ranti àṣẹ tí ó pa fún ẹgbẹẹgbẹrun ìran, majẹmu tí ó bá Abrahamu dá, ìlérí tí ó fi ìbúra ṣe fún Isaaki, tí ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ fún Jakọbu gẹ́gẹ́ bí òfin, àní fún Israẹli gẹ́gẹ́ bíi majẹmu ayérayé, ó ní: “Ẹ̀yin ni n óo fi ilẹ̀ Kenaani fún, yóo jẹ́ ìpín yín tí ẹ óo jogún.” Nígbà tí wọ́n kéré ní iye, tí wọn kò tíì pọ̀ rárá, tí wọn sì jẹ́ àjèjì ní ilẹ̀ náà, tí wọn ń káàkiri láti orílẹ̀-èdè dé orílẹ̀-èdè, láti ìjọba kan dé òmíràn, kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ni wọ́n lára, ó bá àwọn ọba wí nítorí wọn. Ó ní, “Ẹ kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan ẹni àmì òróró mi, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe àwọn wolii mi níbi.”
O. Daf 105:1-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ fi ọpẹ́ fún OLúWA, ké pe orúkọ rẹ̀: Jẹ́ kí a mọ ohun tí ó ṣe láàrín àwọn orílẹ̀-èdè; Kọrin sí i, kọrin ìyìn sí i; sọ ti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ gbogbo. Ṣògo nínú orúkọ mímọ́ rẹ̀: Jẹ́ kí ọkàn àwọn tí ń wá OLúWA kí ó yọ̀. Wá OLúWA àti ipá rẹ̀; wa ojú rẹ̀ nígbà gbogbo. Rántí àwọn ìyanu tí ó ti ṣe, ìyanu rẹ̀, àti ìdájọ́ tí ó sọ, Ẹ̀yin ìran Abrahamu ìránṣẹ́ rẹ̀, ẹ̀yin ọmọkùnrin Jakọbu, àyànfẹ́ rẹ̀. Òun ni OLúWA Ọlọ́run wa: ìdájọ́ rẹ̀ wà ní gbogbo ayé. Ó rántí májẹ̀mú rẹ̀ láéláé, ọ̀rọ̀ tí ó pàṣẹ, fún ẹgbẹgbẹ̀rún ìran, májẹ̀mú tí ó dá pẹ̀lú Abrahamu, ìbúra tí ó ṣe pẹ̀lú fún Isaaki. Ó ṣe ìdánilójú u rẹ̀ fún Jakọbu gẹ́gẹ́ bí àṣẹ sí Israẹli, gẹ́gẹ́ bi májẹ̀mú ayérayé: “Fún ìwọ ni èmi ó fún ní ilẹ̀ Kenaani gẹ́gẹ́ bí ìpín tí ìwọ ó jogún.” Nígbà tí wọn kéré níye, wọ́n kéré jọjọ, àti àwọn àjèjì níbẹ̀ wọ́n rìn kiri láti orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè, láti ìjọba kan sí èkejì. Kò gba ẹnikẹ́ni láààyè láti pọ́n wọn lójú; ó fi ọba bú nítorí tiwọn: “Má ṣe fọwọ́ kan ẹni ààmì òróró mi, má sì ṣe wòlíì mi níbi.”