O. Daf 105:1-15
![O. Daf 105:1-15 - Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa? ẹ pè orukọ rẹ̀: ẹ fi iṣẹ rẹ̀ hàn ninu awọn enia.
Ẹ kọrin si i, ẹ kọ orin mimọ́ si i: ẹ ma sọ̀rọ iṣẹ iyanu rẹ̀ gbogbo.
Ẹ ma ṣogo li orukọ rẹ̀ mimọ́; jẹ ki aiya awọn ti nwá Oluwa ki o yọ̀.
Ẹ ma wá Oluwa ati ipá rẹ̀: ẹ ma wá oju rẹ̀ nigbagbogbo.
Ẹ ma ranti iṣẹ iyanu rẹ̀ ti o ti ṣe; iṣẹ àmi rẹ̀ ati idajọ ẹnu rẹ̀;
Ẹnyin iru-ọmọ Abrahamu iranṣẹ rẹ̀, ẹnyin ọmọ Jakobu, ayanfẹ rẹ̀.
Oluwa, on li Ọlọrun wa: idajọ rẹ̀ mbẹ ni gbogbo aiye.
O ti ranti majẹmu rẹ̀ lailai, ọ̀rọ ti o ti pa li aṣẹ fun ẹgbẹrun iran.
Majẹmu ti o ba Abrahamu dá, ati ibura rẹ̀ fun Isaaki;
O si gbé eyi na kalẹ li ofin fun Jakobu, ati fun Israeli ni majẹmu aiyeraiye.
Pe, iwọ li emi o fi ilẹ Kenaani fun, ipin ilẹ-ini nyin.
Nigbati o ṣe pe kiun ni nwọn wà ni iye; nitõtọ, diẹ kiun, nwọn si ṣe alejo ninu rẹ̀.
Nigbati nwọn nlọ lati orilẹ-ède de orilẹ-ède, lati ijọba kan de ọdọ awọn enia miran;
On kò jẹ ki ẹnikẹni ki o ṣe wọn ni iwọsi: Nitõtọ, o ba awọn ọba wi nitori wọn;
Pe, Ẹ máṣe fi ọwọ kan ẹni-ororo mi ki ẹ má si ṣe awọn woli mi ni ibi](/_next/image?url=https%3A%2F%2Fimageproxy.youversionapi.com%2F320x320%2Fhttps%3A%2F%2Fs3.amazonaws.com%2Fstatic-youversionapi-com%2Fimages%2Fbase%2F51069%2F1280x1280.jpg&w=640&q=75)
Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa? ẹ pè orukọ rẹ̀: ẹ fi iṣẹ rẹ̀ hàn ninu awọn enia. Ẹ kọrin si i, ẹ kọ orin mimọ́ si i: ẹ ma sọ̀rọ iṣẹ iyanu rẹ̀ gbogbo. Ẹ ma ṣogo li orukọ rẹ̀ mimọ́; jẹ ki aiya awọn ti nwá Oluwa ki o yọ̀. Ẹ ma wá Oluwa ati ipá rẹ̀: ẹ ma wá oju rẹ̀ nigbagbogbo. Ẹ ma ranti iṣẹ iyanu rẹ̀ ti o ti ṣe; iṣẹ àmi rẹ̀ ati idajọ ẹnu rẹ̀; Ẹnyin iru-ọmọ Abrahamu iranṣẹ rẹ̀, ẹnyin ọmọ Jakobu, ayanfẹ rẹ̀. Oluwa, on li Ọlọrun wa: idajọ rẹ̀ mbẹ ni gbogbo aiye. O ti ranti majẹmu rẹ̀ lailai, ọ̀rọ ti o ti pa li aṣẹ fun ẹgbẹrun iran. Majẹmu ti o ba Abrahamu dá, ati ibura rẹ̀ fun Isaaki; O si gbé eyi na kalẹ li ofin fun Jakobu, ati fun Israeli ni majẹmu aiyeraiye. Pe, iwọ li emi o fi ilẹ Kenaani fun, ipin ilẹ-ini nyin. Nigbati o ṣe pe kiun ni nwọn wà ni iye; nitõtọ, diẹ kiun, nwọn si ṣe alejo ninu rẹ̀. Nigbati nwọn nlọ lati orilẹ-ède de orilẹ-ède, lati ijọba kan de ọdọ awọn enia miran; On kò jẹ ki ẹnikẹni ki o ṣe wọn ni iwọsi: Nitõtọ, o ba awọn ọba wi nitori wọn; Pe, Ẹ máṣe fi ọwọ kan ẹni-ororo mi ki ẹ má si ṣe awọn woli mi ni ibi
O. Daf 105:1-15