ÌWÉ ÒWE 8:14-26

ÌWÉ ÒWE 8:14-26 YCE

Èmi ni mo ní ìmọ̀ràn ati ọgbọ́n tí ó yè kooro, mo sì ní òye ati agbára. Nípasẹ̀ mi ni àwọn ọba fi ń ṣe ìjọba, tí àwọn alákòóso sì ń pàṣẹ òdodo. Nípasẹ̀ mi ni àwọn olórí ń ṣe àkóso, gbogbo àwọn ọlọ́lá sì ń ṣe àkóso ayé. Mo fẹ́ràn gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ràn mi, àwọn tí wọ́n bá fi tọkàntọkàn wá mi yóo sì rí mi. Ọrọ̀ ati iyì wà níkàáwọ́ mi, ọrọ̀ tíí tọ́jọ́, ati ibukun. Èso mi dára ju wúrà dáradára lọ, àyọrísí mi sì dára ju ojúlówó fadaka lọ. Ọ̀nà òdodo ni èmi ń rìn, ojú ọ̀nà tí ó tọ́ ni mò ń tọ̀. Èmi a máa fún àwọn tí wọ́n fẹ́ mi ní ọrọ̀, n óo máa mú kí ìṣúra wọn kún. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀dá ayé ni OLUWA ti dá mi, kí ó tó bẹ̀rẹ̀ àwọn iṣẹ́ àrà rẹ̀. Láti ayébáyé ni a ti yàn mí, láti ìbẹ̀rẹ̀, kí á tó dá ayé rárá. Kí ibú omi tó wà ni mo ti wà, nígbà tí kò tíì sí àwọn orísun omi. Kí á tó dá àwọn òkè ńlá sí ààyè wọn, kí àwọn òkè kéékèèké tó wà, ni mo ti wà. Kí Ọlọrun tó dá ayé, ati pápá oko, kí ó tó dá erùpẹ̀ ilẹ̀.