Owe 8:14-26
Owe 8:14-26 Bibeli Mimọ (YBCV)
Temi ni ìmọ ati ọgbọ́n ti o yè: emi li oye, emi li agbara. Nipasẹ mi li ọba nṣe akoso, ti awọn olori si nlàna otitọ. Nipasẹ mi li awọn ijoye nṣolori, ati awọn ọ̀lọtọ̀, ani gbogbo awọn onidajọ aiye. Mo fẹ awọn ti o fẹ mi; awọn ti o si wá mi ni kutukutu yio ri mi. Ọrọ̀ ati ọlá mbẹ lọwọ mi, ani ọrọ̀ daradara ati ododo. Ere mi ta wura yọ; nitõtọ, jù wura daradara lọ: ati ọrọ̀ mi jù fadaka àṣayan lọ. Emi nrìn li ọ̀na ododo, larin ipa-ọ̀na idajọ: Ki emi ki o le mu awọn ti o fẹ mi jogun ohun-ini mi, emi o si fi kún iṣura wọn. Oluwa pèse mi ni ipilẹṣẹ ìwa rẹ̀, ṣaju iṣẹ rẹ̀ atijọ. A ti yàn mi lati aiyeraiye, lati ipilẹṣẹ, tabi ki aiye ki o to wà. Nigbati ọgbun kò si, a ti bi mi; nigbati kò si orisun ti o kún fun omi pipọ. Ki a to fi idi awọn òke-nla sọlẹ, ṣãju awọn òke li a ti bi mi: Nigbati kò ti ida aiye, tabi pẹ̀tẹlẹ, tabi ori erupẹ aiye.
Owe 8:14-26 Yoruba Bible (YCE)
Èmi ni mo ní ìmọ̀ràn ati ọgbọ́n tí ó yè kooro, mo sì ní òye ati agbára. Nípasẹ̀ mi ni àwọn ọba fi ń ṣe ìjọba, tí àwọn alákòóso sì ń pàṣẹ òdodo. Nípasẹ̀ mi ni àwọn olórí ń ṣe àkóso, gbogbo àwọn ọlọ́lá sì ń ṣe àkóso ayé. Mo fẹ́ràn gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ràn mi, àwọn tí wọ́n bá fi tọkàntọkàn wá mi yóo sì rí mi. Ọrọ̀ ati iyì wà níkàáwọ́ mi, ọrọ̀ tíí tọ́jọ́, ati ibukun. Èso mi dára ju wúrà dáradára lọ, àyọrísí mi sì dára ju ojúlówó fadaka lọ. Ọ̀nà òdodo ni èmi ń rìn, ojú ọ̀nà tí ó tọ́ ni mò ń tọ̀. Èmi a máa fún àwọn tí wọ́n fẹ́ mi ní ọrọ̀, n óo máa mú kí ìṣúra wọn kún. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀dá ayé ni OLUWA ti dá mi, kí ó tó bẹ̀rẹ̀ àwọn iṣẹ́ àrà rẹ̀. Láti ayébáyé ni a ti yàn mí, láti ìbẹ̀rẹ̀, kí á tó dá ayé rárá. Kí ibú omi tó wà ni mo ti wà, nígbà tí kò tíì sí àwọn orísun omi. Kí á tó dá àwọn òkè ńlá sí ààyè wọn, kí àwọn òkè kéékèèké tó wà, ni mo ti wà. Kí Ọlọrun tó dá ayé, ati pápá oko, kí ó tó dá erùpẹ̀ ilẹ̀.
Owe 8:14-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìmọ̀ràn àti ọgbọ́n tí ó yè kooro jẹ́ tèmi mo ní òye àti agbára. Nípasẹ̀ mi ni ọba ń ṣàkóso tí àwọn aláṣẹ sì ń ṣe òfin tí ó dára Nípasẹ̀ mi àwọn ọmọ-aládé ń ṣàkóso àti gbogbo ọlọ́lá tí ń ṣàkóso ilẹ̀ ayé. Mo fẹ́ràn àwọn tí ó fẹ́ràn mi àwọn tí ó sì wá mi rí mi. Lọ́dọ̀ mi ni ọrọ̀ àti ọlá wà ọrọ̀ tí í tọ́jọ́ àti ìgbéga rere. Èso mi dára ju wúrà dáradára lọ; ohun tí mò ń mú wá ju àṣàyàn fàdákà lọ. Mò ń rìn ní ọ̀nà òdodo, ní ojú ọ̀nà òtítọ́, Mò ń fi ọrọ̀ fún gbogbo àwọn tí ó fẹ́ràn mi mo sì ń mú kí ilé ìṣúra wọn kún. “Èmi ni OLúWA kọ́kọ́ dá nínú iṣẹ́ rẹ̀. Ṣáájú àwọn iṣẹ́ rẹ̀ àtijọ́; A ti yàn mí láti ayérayé, láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, kí ayé tó bẹ̀rẹ̀. Nígbà tí kò tí ì sí Òkun, ni a ti bí mi nígbà tí kò tí ì sí ìsun tí ó ní omi nínú; kí a tó fi àwọn òkè sí ipò wọn, ṣáájú àwọn òkè ni a ti bí mi, kí ó tó dá ilẹ̀ ayé tàbí àwọn oko rẹ̀ tàbí èyíkéyìí nínú eruku ayé.