ÌWÉ ÒWE 28

28
1Àwọn eniyan burúkú a máa sá,
nígbà tí ẹnikẹ́ni kò lé wọn,
ṣugbọn olódodo a máa láyà bíi kinniun.
2Bí orílẹ̀-èdè kan bá dẹ́ṣẹ̀,
léraléra ni wọ́n ó máa jọba,
ṣugbọn bí orílẹ̀-èdè kan bá ní àwọn eniyan tí wọn ní òye ati ìmọ̀,
yóo wà fún ìgbà pípẹ́.
3Talaka tí ń ni aláìní lára
dàbí òjò líle tí ó ba nǹkan ọ̀gbìn jẹ́.
4Àwọn tí wọ́n kọ òfin sílẹ̀
ni wọ́n máa ń yin àwọn eniyan burúkú,
ṣugbọn àwọn tí wọn ń pa òfin mọ́ máa ń dojú ìjà kọ wọ́n.
5Òye ìdájọ́ òdodo kò yé àwọn eniyan burúkú,
ṣugbọn ó yé àwọn tí ń wá OLUWA yékéyéké.
6Talaka tí ń rìn pẹlu òtítọ́ inú
sàn ju ọlọ́rọ̀ tí ń hùwà àgàbàgebè lọ.
7Ọlọ́gbọ́n ọmọ ni ọmọ tí ó pa òfin mọ́,
ṣugbọn ẹni tí ń bá àwọn wọ̀bìà rìn, ń dójúti baba rẹ̀.
8Ẹni tí ó ń fi kún ọrọ̀ rẹ̀ nípa gbígba èlé
ati èrè jíjẹ ní ọ̀nà èrú,
ń kó ọrọ̀ náà jọ fún ẹni tí yóo ṣàánú àwọn talaka.
9Ẹni tí ó kọ etí dídi sí òfin Ọlọrun,
adura rẹ̀ pàápàá yóo di ìríra sí Ọlọ́run.
10Ẹni tí ó ṣi olódodo lọ́nà lọ sinu ibi,
yóo já sinu kòtò tí òun fúnrarẹ̀ gbẹ́ sílẹ̀,
ṣugbọn aláìlẹ́bi eniyan yóo jogún ire.
11Ọlọ́rọ̀ gbọ́n lójú ara rẹ̀,
ṣugbọn talaka tí ó gbọ́n yóo rídìí rẹ̀.
12Nígbà tí olódodo bá borí, àwọn eniyan á yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀,
ṣugbọn nígbà tí ìkà bá dìde, àwọn eniyan á sá pamọ́.
13Ẹni tí ó bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ kò ní ṣe rere,
ṣugbọn ẹni tí ó jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,
tí ó sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀, yóo rí àánú gbà.
14Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó ń bẹ̀rù OLUWA nígbà gbogbo,
ṣugbọn ẹni tí ó sé ọkàn rẹ̀ le yóo bọ́ sinu ìyọnu.
15Ọba burúkú tí ó jọba lórí àwọn talaka,
dàbí kinniun tí ń bú ramúramù,
tabi ẹranko beari tí inú ń bí.
16Ìkà, aninilára ni olórí tí kò ní òye,
ṣugbọn ẹ̀mí ẹni tí ó bá kórìíra à ń jèrè lọ́nà èrú yóo gùn.
17Bí ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ ẹnìkan bá ń da eniyan láàmú,
yóo di ìsáǹsá ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀,
kí ẹnikẹ́ni má ṣe ràn án lọ́wọ́.
18Ẹni tí ń rìn pẹlu òtítọ́ inú yóo rí ìgbàlà,
ṣugbọn ẹni tí ń rìn ségesège yóo ṣubú sinu kòtò.
19Ẹni tí ń ṣiṣẹ́ oko dáradára, yóo ní oúnjẹ pupọ,
ṣugbọn ẹni tí ń fi àkókò rẹ̀ ṣòfò yóo di talaka.
20Olóòótọ́ yóo ní ibukun lọpọlọpọ,
ṣugbọn ẹni tí ń kánjú àtilówó, kò ní lọ láìjìyà.
21Ojuṣaaju kò dára,
sibẹ oúnjẹ lè mú kí eniyan ṣe ohun tí kò tọ́.
22Ahun a máa sáré ati ní ọrọ̀,
láìmọ̀ pé òṣì ń bọ̀ wá ta òun.
23Ẹni tí ó bá eniyan wí,
yóo rí ojurere níkẹyìn,
ju ẹni tí ń pọ́n eniyan lọ.
24Ẹni tí ó ja ìyá tabi baba rẹ̀ lólè,
tí ó ní, “Kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀”,
ẹlẹgbẹ́ apanirun ni.
25Olójúkòkòrò eniyan a máa dá ìjà sílẹ̀,
ṣugbọn ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLUWA yóo ṣe rere.
26Òmùgọ̀ ni ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀lé ara rẹ̀,
ẹni tí ń fi ọgbọ́n rìn yóo là.
27Ẹni tí ó ta talaka lọ́rẹ kò ní ṣe aláìní,
ṣugbọn ẹni tí ó fojú pamọ́ fún wọn, yóo gba ègún.
28Nígbà tí àwọn eniyan burúkú bá dìde,
àwọn eniyan á sá pamọ́,
ṣugbọn nígbà tí wọ́n bá parun, olódodo á pọ̀ sí i.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ÌWÉ ÒWE 28: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀