ÌWÉ ÒWE 29

29
1Ẹni tí à ń báwí tí ó ń ṣoríkunkun,
yóo parun lójijì láìsí àtúnṣe.
2Nígbà tí olódodo bá di eniyan pataki,
àwọn eniyan a máa yọ̀,
ṣugbọn nígbà tí eniyan burúkú bá wà lórí oyè,
àwọn eniyan a máa kérora.
3Ọlọ́gbọ́n ọmọ a máa mú inú baba rẹ̀ dùn,
ṣugbọn ẹni tí ń tẹ̀lé aṣẹ́wó kiri, ń fi ọrọ̀ ara rẹ̀ ṣòfò.
4Ọba tí ó bá ń ṣe ìdájọ́ òdodo, a máa fìdí orílẹ̀-èdè múlẹ̀,
ṣugbọn ọba onírìbá a máa dojú orílẹ̀-èdè bolẹ̀.
5Ẹni tí ó bá ń pọ́n aládùúgbò rẹ̀,
ń dẹ àwọ̀n sílẹ̀ fún ẹsẹ̀ rẹ̀.
6Eniyan burúkú bọ́ sinu àwọ̀n ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,
ṣugbọn olódodo lè kọrin, ó sì lè máa yọ̀.
7Olódodo a máa bìkítà fún ẹ̀tọ́ àwọn talaka,
ṣugbọn àwọn eniyan burúkú kò ní òye irú rẹ̀.
8Àwọn ẹlẹ́gàn a máa dá rúkèrúdò sílẹ̀ láàrin ìlú,
ṣugbọn àwọn ọlọ́gbọ́n a máa paná ibinu.
9Nígbà tí ọlọ́gbọ́n bá pe òmùgọ̀ lẹ́jọ́,
ẹ̀rín ni òmùgọ̀ yóo máa fi rín,
yóo máa pariwo, kò sì ní dákẹ́.
10Àwọn apànìyàn kórìíra olóòótọ́ inú,
wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti pa á.
11Òmùgọ̀ eniyan a máa bínú,
ṣugbọn ọlọ́gbọ́n a máa mú sùúrù.
12Bí aláṣẹ bá ń fetí sí irọ́,
gbogbo àwọn ìgbìmọ̀ rẹ̀ yóo di eniyankeniyan.
13Ohun tí ó sọ talaka ati aninilára di ọ̀kan náà ni pé,
OLUWA ló fún àwọn mejeeji ní ojú láti ríran.
14Ọba tí ó dájọ́ ẹ̀tọ́ fún talaka,
ní a óo fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ títí.
15Pàṣán ati ìbáwí a máa kọ́ ọmọ lọ́gbọ́n,
ọmọ tí a bá fi sílẹ̀ yóo dójúti ìyá rẹ̀.
16Nígbà tí eniyan burúkú bá wà lórí oyè, ẹ̀ṣẹ̀ a máa pọ̀ síi,
ṣugbọn lójú olódodo ni wọn yóo ti ṣubú.
17Tọ́ ọmọ rẹ, yóo sì fún ọ ní ìsinmi,
yóo sì mú inú rẹ dùn.
18Orílẹ̀-èdè tí kò bá ní ìfihàn láti ọ̀run, yóo dàrú,
ṣugbọn ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ń pa òfin mọ́.
19Ọ̀rọ̀ ẹnu nìkan kò tó láti fi bá ẹrú wí,#Sir 33:25-30
ó lè fi etí gbọ́ ṣugbọn kí ó má ṣe ohunkohun.
20Òmùgọ̀ nírètí ju ẹni tí yóo sọ̀rọ̀ sọ̀rọ̀,
tí kò lè kó ara rẹ̀ ní ìjánu lọ.
21Bí eniyan bá kẹ́ ẹrú ní àkẹ́jù,
yóo ya ìyàkuyà níkẹyìn.
22Ẹni tí inú ń bí a máa dá rògbòdìyàn sílẹ̀,
onínúfùfù a sì máa ṣe ọpọlọpọ àṣìṣe.
23Ìgbéraga eniyan a máa rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀,
ṣugbọn onírẹ̀lẹ̀ ọkàn yóo gba iyì.
24Ẹni tí ó ṣe alábàápín pẹlu olè kò fẹ́ràn ẹ̀mí ara rẹ̀,
ó gbọ́ ọ̀rọ̀ ègún, ṣugbọn kò sọ fún ẹnikẹ́ni.
25Ìbẹ̀rù eniyan a máa di ìdẹkùn fún eniyan,
ṣugbọn ẹni bá gbẹ́kẹ̀lé OLUWA yóo wà láìléwu.
26Ọ̀pọ̀ ń wá ojurere olórí,
ṣugbọn OLUWA níí dáni ní ẹjọ́ òdodo.
27Olódodo a máa kórìíra alaiṣootọ,
eniyan burúkú a sì kórìíra eniyan rere.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ÌWÉ ÒWE 29: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa