ÌWÉ ÒWE 27

27
1Má lérí nípa ọ̀la,#Jak 4:13-16
nítorí o kò mọ ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan.
2Ẹlòmíràn ni kí o jẹ́ kí ó yìn ọ́, má yin ara rẹ,
jẹ́ kí ó ti ẹnu ẹlòmíràn jáde,
kí ó má jẹ́ láti ẹnu ìwọ alára.
3Òkúta wúwo, yanrìn sì tẹ̀wọ̀n,
ṣugbọn ìmúnibínú aṣiwèrè wúwo lọ́kàn ẹni ju mejeeji lọ.
4Ìkà ni ibinu, ìrúnú sì burú lọpọlọpọ,
ṣugbọn, ta ló lè dúró níwájú owú jíjẹ?
5Ìbáwí ní gbangba sàn ju ìfẹ́ kọ̀rọ̀ lọ.
6Òtítọ́ ọ̀rọ̀ ọ̀rẹ́ ẹni lè dunni bí ọgbẹ́;
ṣugbọn ẹ̀tàn ni ìfẹnukonu ọ̀tá.
7Ẹni tí ó yó lè wo oyin ní àwòmọ́jú,
ṣugbọn bí nǹkan tilẹ̀ korò a máa dùn,
lẹ́nu ẹni tí ebi ń pa.
8Ẹni tí ó ṣìnà ilé rẹ̀,
dàbí ẹyẹ tí ó ṣìnà ìtẹ́ rẹ̀.
9Òróró ati turari a máa mú inú dùn,
ṣugbọn láti inú ìmọ̀ràn òtítọ́ ni adùn ọ̀rẹ́ ti ń wá.
10Má pa àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tì ati àwọn ọ̀rẹ́ baba rẹ;
má sì lọ sí ilé arakunrin rẹ ní ọjọ́ ìṣòro rẹ.
Nítorí pé aládùúgbò tí ó súnmọ́ ni sàn ju arakunrin tí ó jìnnà sí ni lọ.
11Ọmọ mi, gbọ́n, kí o sì mú inú mi dùn,
kí n lè rí ẹnu dá àwọn tí wọn ń pẹ̀gàn mi lóhùn.
12Amòye eniyan rí ewu, ó sì fi ara rẹ̀ pamọ́,
ṣugbọn òpè kọjá lọ láàrin rẹ̀, ó sì jìyà rẹ̀.
13Gba ẹ̀wù ẹni tí ó bá ṣe onídùúró fún àlejò,
kí o sì gba nǹkan ìdógò lọ́wọ́ rẹ̀,
tí ó bá ṣe onídùúró fún àjèjì obinrin.
14Ẹni tí ó jí ní kutukutu òwúrọ̀,
tí ó ń fi ariwo kí aládùúgbò rẹ̀,
kò yàtọ̀ sí ẹni tí ń ṣépè.
15Iyawo oníjà dàbí omi òjò,
tí ń kán tó! Tó! Tó! Láì dáwọ́ dúró;
16ẹni tí bá ń gbìyànjú láti dá irú obinrin bẹ́ẹ̀ lẹ́kun
dàbí ẹni tí ń gbìyànjú láti dá afẹ́fẹ́ dúró,
tabi ẹni tó fẹ́ fi ọwọ́ mú epo.
17Bí irin ti ń pọ́n irin,
bẹ́ẹ̀ ni eniyan ń kẹ́kọ̀ọ́ lára ẹnìkejì rẹ̀.
18Ẹni tí ń tọ́jú igi ọ̀pọ̀tọ́ yóo rí èso rẹ̀ jẹ,
ẹni tí ń tọ́jú ọ̀gá rẹ̀ yóo gba ìyìn rẹ̀.
19Bí omi tíí fi bí ojú ẹni ti rí han ni,
bẹ́ẹ̀ ni ọkàn eniyan ń fi irú ẹni tí eniyan jẹ́ hàn.
20Ìparun ati isà òkú kò lè ní ìtẹ́lọ́rùn,
bẹ́ẹ̀ náà ni ojú eniyan, kì í ní ìtẹ́lọ́rùn.
21Iná ni a fi ń dán wúrà ati fadaka wò,
ìyìn ni a fi ń dán eniyan wò.
22Wọn ì báà ju òmùgọ̀ sinu odó,
kí wọn fi ọmọ odó gún un pọ̀ mọ́ ọkà,
ẹnìkan kò lè gba ìwà òmùgọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀.
23Rí i dájú pé o mọ̀ bí agbo ẹran rẹ ti rí,
sì máa tọ́jú ọ̀wọ́ ẹran rẹ dáradára;
24nítorí ọrọ̀ kì í pẹ́ lọ títí,
kí adé pẹ́ lórí kì í ṣe láti ìrandíran.
25Lẹ́yìn tí a bá gé koríko, tí koríko tútù mìíràn sì hù,
tí a bá kó koríko tí a gé lára àwọn òkè wálé,
26o óo rí irun aguntan fi hun aṣọ,
o óo sì lè fi owó tí o bá pa lórí àwọn ewúrẹ́ rẹ ra ilẹ̀.
27O óo rí omi wàrà ewúrẹ́ rẹ fún, tí o óo máa rí mu,
ìwọ ati ìdílé rẹ, ati àwọn iranṣẹbinrin rẹ pẹlu.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ÌWÉ ÒWE 27: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀