Ibi tí àwọn ọmọ Israẹli pàgọ́ sí ninu ìrìn àjò wọn láti ìgbà tí wọn ti kúrò ní Ijipti lábẹ́ àṣẹ Mose ati Aaroni nìwọ̀nyí: (Orúkọ gbogbo ibi tí wọ́n pàgọ́ sí ni Mose ń kọ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àṣẹ OLUWA.) Àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní Ramesesi ní Ijipti ní ọjọ́ kẹẹdogun oṣù kinni, ní ọjọ́ keji Àjọ̀dún Ìrékọjá pẹlu ọwọ́ agbára OLUWA, níṣojú àwọn ará Ijipti, tí wọn ń sin òkú àwọn àkọ́bí wọn tí OLUWA pa, OLUWA fihàn pé òun ní agbára ju oriṣa àwọn ará Ijipti lọ. Àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní Ramesesi, wọ́n lọ pàgọ́ sí Sukotu. Wọ́n kúrò ní Sukotu, wọ́n lọ pàgọ́ sí Etamu tí ó wà létí aṣálẹ̀. Láti ibẹ̀ wọ́n pada sẹ́yìn lọ sí Pi Hahirotu tí ó wà níwájú Baali Sefoni, wọ́n pàgọ́ siwaju Migidoli. Wọ́n kúrò níwájú Pi Hahirotu, wọ́n la ààrin òkun kọjá lọ sinu aṣálẹ̀. Lẹ́yìn ìrìn ọjọ́ mẹta ninu aṣálẹ̀ Etamu, wọ́n pàgọ́ sí Mara. Wọ́n kúrò ní Mara, wọ́n lọ pàgọ́ sí Elimu níbi tí orísun omi mejila ati aadọrin igi ọ̀pẹ wà. Wọ́n kúrò ní Elimu, wọ́n lọ pàgọ́ sí etí Òkun Pupa. Wọ́n kúrò níbẹ̀, wọ́n lọ pàgọ́ sí aṣálẹ̀ Sini. Wọ́n kúrò ní aṣálẹ̀ Sini, wọ́n lọ pàgọ́ sí Dofika. Wọ́n kúrò ní Dofika, wọ́n lọ pàgọ́ sí Aluṣi. Wọ́n kúrò ní Aluṣi, wọ́n lọ pàgọ́ sí Refidimu níbi tí wọn kò ti rí omi mu. Wọ́n kúrò ní Refidimu lọ sí aṣálẹ̀ Sinai. Láti aṣálẹ̀ Sinai wọ́n lọ sí Kiburotu Hataafa. Láti Kiburotu Hataafa wọ́n lọ sí Haserotu. Láti Haserotu wọ́n lọ sí Ritima. Láti Ritima wọ́n lọ sí Rimoni Peresi. Láti Rimoni Peresi wọ́n lọ sí Libina. Láti Libina wọ́n lọ sí Risa. Láti Risa wọ́n lọ sí Kehelata. Láti Kehelata wọ́n lọ sí Òkè Ṣeferi. Láti Òkè Ṣeferi wọ́n lọ sí Harada. Láti Harada wọ́n lọ sí Makihelotu. Láti Makihelotu wọ́n lọ sí Tahati. Láti Tahati wọ́n lọ sí Tẹra. Láti Tẹra wọ́n lọ sí Mitika. Láti Mitika wọ́n lọ sí Haṣimona. Láti Haṣimona wọ́n lọ sí Moserotu. Láti Moserotu wọ́n lọ sí Bene Jaakani. Láti Bene Jaakani wọ́n lọ sí Hori Hagidigadi. Láti Hori Hagidigadi wọ́n lọ sí Jotibata. Láti Jotibata wọ́n lọ sí Abirona. Láti Abirona wọ́n lọ sí Esiongeberi. Láti Esiongeberi wọ́n lọ sí aṣálẹ̀ Sini, tíí ṣe Kadeṣi. Láti Kadeṣi wọ́n lọ sí Òkè Hori, lẹ́bàá ilẹ̀ Edomu. Aaroni alufaa gun Òkè Hori lọ bí OLUWA ti pa á láṣẹ fún un, níbẹ̀ ni ó sì kú sí ní ọjọ́ kinni oṣù karun-un, ogoji ọdún lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní Ijipti. Aaroni jẹ́ ẹni ọdún mẹtalelọgọfa (123) nígbà tí ó kú ní Òkè Hori.
Kà NỌMBA 33
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: NỌMBA 33:1-39
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò