Num 33:1-39

Num 33:1-39 Bibeli Mimọ (YBCV)

WỌNYI ni ìrin awọn ọmọ Israeli, ti o ti ilẹ Egipti jade wá pẹlu awọn ogun wọn, nipa ọwọ́ Mose ati Aaroni. Mose si kọwe ijadelọ wọn gẹgẹ bi ìrin wọn, nipa aṣẹ OLUWA; wọnyi si ni ìrin wọn gẹgẹ bi ijadelọ wọn. Nwọn si ṣí kuro ni Ramesesi li oṣù kini, ni ijọ́ kẹdogun oṣù kini na; ni ijọ́ keji ajọ irekọja li awọn ọmọ Israeli jade pẹlu ọwọ́ giga li oju gbogbo awọn ara Egipti. Bi awọn ara Egipti ti nsinkú gbogbo awọn akọ́bi wọn ti OLUWA kọlù ninu wọn: lara awọn oriṣa wọn pẹlu li OLUWA ṣe idajọ. Awọn ọmọ Israeli si ṣí kuro ni Ramesesi, nwọn si dó si Sukkotu. Nwọn si ṣí kuro ni Sukkotu, nwọn si dó si Etamu, ti mbẹ leti aginjù. Nwọn si ṣí kuro ni Etamu, nwọn si pada lọ si Pi-hahirotu, ti mbẹ niwaju Baali-sefoni: nwọn si dó siwaju Migdolu. Nwọn si ṣí kuro niwaju Hahirotu, nwọn si là ãrin okun já lọ si aginjù: nwọn si rìn ìrin ijọ́ mẹta li aginjù Etamu, nwọn si dó si Mara. Nwọn si ṣí kuro ni Mara, nwọn si wá si Elimu: ni Elimu ni orisun omi mejila, ati ãdọrin igi ọpẹ wà; nwọn si dó sibẹ̀. Nwọn si ṣí kuro ni Elimu, nwọn si dó si ẹba Okun Pupa. Nwọn si ṣí kuro li Okun Pupa, nwọn si dó si aginjù Sini. Nwọn si ṣí kuro ni aginjù Sini, nwọn si dó si Dofka. Nwọn si ṣí kuro ni Dofka, nwọn si dó si Aluṣi. Nwọn si ṣí kuro ni Aluṣi, nwọn si dó si Refidimu, nibiti omi kò gbé sí fun awọn enia na lati mu. Nwọn si ṣí kuro ni Refidimu, nwọn si dó si aginjù Sinai. Nwọn si ṣí kuro ni aginjù Sinai, nwọn si dó si Kibrotu-hattaafa. Nwọn si ṣí kuro ni Kibrotu-hattaafa, nwọn si dó si Haserotu. Nwọn si ṣí kuro ni Haserotu, nwọn si dó si Ritma. Nwọn si ṣí kuro ni Ritma, nwọn si dó si Rimmon-peresi. Nwọn si ṣí kuro ni Rimmon-peresi, nwọn si dó si Libna. Nwọn si ṣí kuro ni Libna, nwọn si dó si Rissa. Nwọn si ṣí kuro ni Rissa, nwọn si dó si Kehelata. Nwọn si ṣí kuro ni Kehelata, nwọn si dó si òke Ṣeferi. Nwọn si ṣí kuro ni òke Ṣeferi, nwọn si dó si Harada. Nwọn si ṣí kuro ni Harada, nwọn si dó si Makhelotu. Nwọn si ṣí kuro ni Makhelotu, nwọn si dó si Tahati. Nwọn si ṣí kuro ni Tahati, nwọn si dó si Tera. Nwọn si ṣí kuro ni Tera, nwọn si dó si Mitka. Nwọn si ṣí kuro ni Mitka, nwọn si dó si Haṣmona. Nwọn si ṣí kuro ni Haṣmona, nwọn si dó si Moserotu. Nwọn si ṣí kuro ni Moserotu, nwọn si dó si Bene-jaakani. Nwọn si ṣí kuro ni Bene-jaakani, nwọn si dó si Hori-haggidgadi. Nwọn si ṣí kuro ni Hori-haggidgadi, nwọn si dó si Jotbata. Nwọn si ṣí kuro ni Jotbata, nwọn si dó si Abrona. Nwọn si ṣí kuro ni Abrona, nwọn si dó si Esion-geberi. Nwọn si ṣí kuro ni Esion-geberi, nwọn si dó si aginjù Sini, (ti ṣe Kadeṣi), Nwọn si ṣí kuro ni Kadeṣi, nwọn si dó si òke Hori, leti ilẹ Edomu. Aaroni alufa si gùn òke Hori lọ nipa aṣẹ OLUWA, o si kú nibẹ̀, li ogoji ọdún lẹhin ti awọn ọmọ Israeli ti ilẹ Egipti jade wá, li ọjọ́ kini oṣù karun. Aaroni si jẹ́ ẹni ọgọfa ọdún o le mẹta nigbati o kú li òke Hori.

Num 33:1-39 Yoruba Bible (YCE)

Ibi tí àwọn ọmọ Israẹli pàgọ́ sí ninu ìrìn àjò wọn láti ìgbà tí wọn ti kúrò ní Ijipti lábẹ́ àṣẹ Mose ati Aaroni nìwọ̀nyí: (Orúkọ gbogbo ibi tí wọ́n pàgọ́ sí ni Mose ń kọ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àṣẹ OLUWA.) Àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní Ramesesi ní Ijipti ní ọjọ́ kẹẹdogun oṣù kinni, ní ọjọ́ keji Àjọ̀dún Ìrékọjá pẹlu ọwọ́ agbára OLUWA, níṣojú àwọn ará Ijipti, tí wọn ń sin òkú àwọn àkọ́bí wọn tí OLUWA pa, OLUWA fihàn pé òun ní agbára ju oriṣa àwọn ará Ijipti lọ. Àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní Ramesesi, wọ́n lọ pàgọ́ sí Sukotu. Wọ́n kúrò ní Sukotu, wọ́n lọ pàgọ́ sí Etamu tí ó wà létí aṣálẹ̀. Láti ibẹ̀ wọ́n pada sẹ́yìn lọ sí Pi Hahirotu tí ó wà níwájú Baali Sefoni, wọ́n pàgọ́ siwaju Migidoli. Wọ́n kúrò níwájú Pi Hahirotu, wọ́n la ààrin òkun kọjá lọ sinu aṣálẹ̀. Lẹ́yìn ìrìn ọjọ́ mẹta ninu aṣálẹ̀ Etamu, wọ́n pàgọ́ sí Mara. Wọ́n kúrò ní Mara, wọ́n lọ pàgọ́ sí Elimu níbi tí orísun omi mejila ati aadọrin igi ọ̀pẹ wà. Wọ́n kúrò ní Elimu, wọ́n lọ pàgọ́ sí etí Òkun Pupa. Wọ́n kúrò níbẹ̀, wọ́n lọ pàgọ́ sí aṣálẹ̀ Sini. Wọ́n kúrò ní aṣálẹ̀ Sini, wọ́n lọ pàgọ́ sí Dofika. Wọ́n kúrò ní Dofika, wọ́n lọ pàgọ́ sí Aluṣi. Wọ́n kúrò ní Aluṣi, wọ́n lọ pàgọ́ sí Refidimu níbi tí wọn kò ti rí omi mu. Wọ́n kúrò ní Refidimu lọ sí aṣálẹ̀ Sinai. Láti aṣálẹ̀ Sinai wọ́n lọ sí Kiburotu Hataafa. Láti Kiburotu Hataafa wọ́n lọ sí Haserotu. Láti Haserotu wọ́n lọ sí Ritima. Láti Ritima wọ́n lọ sí Rimoni Peresi. Láti Rimoni Peresi wọ́n lọ sí Libina. Láti Libina wọ́n lọ sí Risa. Láti Risa wọ́n lọ sí Kehelata. Láti Kehelata wọ́n lọ sí Òkè Ṣeferi. Láti Òkè Ṣeferi wọ́n lọ sí Harada. Láti Harada wọ́n lọ sí Makihelotu. Láti Makihelotu wọ́n lọ sí Tahati. Láti Tahati wọ́n lọ sí Tẹra. Láti Tẹra wọ́n lọ sí Mitika. Láti Mitika wọ́n lọ sí Haṣimona. Láti Haṣimona wọ́n lọ sí Moserotu. Láti Moserotu wọ́n lọ sí Bene Jaakani. Láti Bene Jaakani wọ́n lọ sí Hori Hagidigadi. Láti Hori Hagidigadi wọ́n lọ sí Jotibata. Láti Jotibata wọ́n lọ sí Abirona. Láti Abirona wọ́n lọ sí Esiongeberi. Láti Esiongeberi wọ́n lọ sí aṣálẹ̀ Sini, tíí ṣe Kadeṣi. Láti Kadeṣi wọ́n lọ sí Òkè Hori, lẹ́bàá ilẹ̀ Edomu. Aaroni alufaa gun Òkè Hori lọ bí OLUWA ti pa á láṣẹ fún un, níbẹ̀ ni ó sì kú sí ní ọjọ́ kinni oṣù karun-un, ogoji ọdún lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní Ijipti. Aaroni jẹ́ ẹni ọdún mẹtalelọgọfa (123) nígbà tí ó kú ní Òkè Hori.

Num 33:1-39 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Wọ̀nyí ni ìrìnàjò àwọn ọmọ Israẹli ní ẹsẹẹsẹ, nígbà tí wọ́n tí ilẹ̀ Ejibiti jáde wá pẹ̀lú àwọn ogun wọn, nípa ọwọ́ Mose àti Aaroni. Mose sì kọ̀wé ìjáde lọ wọn ní ẹsẹẹsẹ gẹ́gẹ́ bí ìrìnàjò wọn, nípa àṣẹ OLúWA; Wọ̀nyí sì ni ìrìnàjò wọn gẹ́gẹ́ bí ìjáde lọ wọn. Àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò láti Ramesesi ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù kìn-ín-ní, ọjọ́ kan lẹ́yìn àjọ Ìrékọjá. Wọ́n yan jáde pẹ̀lú ìgboyà níwájú gbogbo àwọn ará Ejibiti. Tí wọ́n sì ń sin gbogbo àkọ́bí wọn, ẹni tí OLúWA ti gbé lulẹ̀ láàrín wọn; nítorí tí OLúWA ti mú ẹ̀san wá sórí àwọn òrìṣà wọn. Àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní Ramesesi wọ́n sì pàgọ́ sí Sukkoti. Wọ́n kúrò ní Sukkoti, wọ́n sì pàgọ́ sí Etamu, ní ẹ̀bá aginjù. Wọ́n kúrò ní Etamu, wọ́n padà sí Pi-Hahirotu sí ìlà-oòrùn Baali-Ṣefoni, wọ́n sì pàgọ́ sí ẹ̀bá Migdoli. Wọ́n sì dìde láti lọ kúrò ní iwájú Pi-Hahirotu, wọ́n sì la àárín Òkun kọjá lọ sí aginjù: Wọ́n sì rin ìrìn ọjọ́ mẹ́ta ní aginjù Etamu, wọ́n sì pàgọ́ sí Mara. Wọ́n kúrò ní Mara wọ́n sì lọ sí Elimu, níbi tí orísun omi méjìlá (12) àti igi ọ̀pẹ àádọ́rin (70) gbé wà, wọ́n sì pàgọ́ níbẹ̀. Wọ́n kúrò ní Elimu wọ́n sì pàgọ́ sí ẹ̀bá Òkun Pupa. Wọ́n kúrò ní ẹ̀bá Òkun Pupa wọ́n sì pàgọ́ sínú aginjù Sini. Wọ́n kúrò nínú aginjù Sini wọ́n sì pàgọ́ sí aginjù Dofka. Wọ́n kúrò ní Dofka wọ́n sì pàgọ́ ní Aluṣi. Wọ́n kúrò ní Aluṣi wọ́n sì pàgọ́ ní Refidimu níbi tí kò sí omi fún àwọn ènìyàn náà láti mu. Wọ́n kúrò ní Refidimu wọ́n sì pàgọ́ ní aginjù Sinai. Wọ́n kúrò ní aginjù Sinai wọ́n sì pàgọ́ ní Kibirotu-Hattaafa. Wọ́n kúrò ní Kibirotu-Hattaafa wọ́n sì pàgọ́ ní Haserotu. Wọ́n kúrò ní Haserotu wọ́n sì pàgọ́ ní Ritma. Wọ́n kúrò ní Ritma wọ́n sì pàgọ́ ní Rimoni-Peresi. Wọ́n kúrò ní Rimoni-Peresi wọ́n sì pàgọ́ ní Libina. Wọ́n kúrò ní Libina wọ́n sì pàgọ́ ní Rissa. Wọ́n kúrò ní Rissa wọ́n sì pàgọ́ ní Kehelata. Wọ́n kúrò ní Kehelata wọ́n sì pàgọ́ ní orí òkè Ṣeferi. Wọ́n kúrò lórí òkè Ṣeferi wọ́n sì pàgọ́ ní Harada. Wọ́n kúrò ní Harada wọ́n sì pàgọ́ ní Makhelotu. Wọ́n kúrò ní Makhelotu wọ́n sì pàgọ́ ní Tahati. Wọ́n kúrò ní Tahati wọ́n sì pàgọ́ ní Tẹra. Wọ́n kúrò ní Tẹra wọ́n sì pàgọ́ ní Mitka. Wọ́n kúrò ní Mitka wọ́n pàgọ́ ní Haṣmona. Wọ́n kúrò ní Haṣmona wọ́n sì pàgọ́ ní Moserotu. Wọ́n kúrò ní Moserotu wọ́n sì pàgọ́ ní Bene-Jaakani. Wọ́n kúrò ní Bene-Jaakani wọ́n sì pàgọ́ ní Hori-Haggidgadi. Wọ́n kúrò ní Hori-Haggidgadi wọ́n sí pàgọ́ ní Jotbata. Wọ́n kúrò ní Jotbata wọ́n sì pàgọ́ ní Abrona. Wọ́n kúrò ní Abrona wọ́n sì pàgọ́ ní Esioni-Geberi. Wọ́n kúrò ní Esioni-Geberi wọ́n sì pàgọ́ ní Kadeṣi nínú aginjù Sini. Wọ́n kúrò ní Kadeṣi wọ́n sì pàgọ́ ní orí òkè Hori, lẹ́bàá Edomu. Nípa àṣẹ OLúWA, Aaroni àlùfáà gùn orí òkè Hori, níbẹ̀ ni ó kú. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù karùn-ún, ọdún ogójì, lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Israẹli ti ilẹ̀ Ejibiti jáde wá. Aaroni jẹ́ ẹni ọgọ́fà ọdún ó-lé-mẹ́ta ní ìgbà tí ó kú sí orí òkè Hori.