NỌMBA 33

33
Ìrìn Àjò láti Ijipti sí Moabu
1Ibi tí àwọn ọmọ Israẹli pàgọ́ sí ninu ìrìn àjò wọn láti ìgbà tí wọn ti kúrò ní Ijipti lábẹ́ àṣẹ Mose ati Aaroni nìwọ̀nyí: 2(Orúkọ gbogbo ibi tí wọ́n pàgọ́ sí ni Mose ń kọ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àṣẹ OLUWA.)
3Àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní Ramesesi ní Ijipti ní ọjọ́ kẹẹdogun oṣù kinni, ní ọjọ́ keji Àjọ̀dún Ìrékọjá pẹlu ọwọ́ agbára OLUWA, níṣojú àwọn ará Ijipti, 4tí wọn ń sin òkú àwọn àkọ́bí wọn tí OLUWA pa, OLUWA fihàn pé òun ní agbára ju oriṣa àwọn ará Ijipti lọ.
5Àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní Ramesesi, wọ́n lọ pàgọ́ sí Sukotu. 6Wọ́n kúrò ní Sukotu, wọ́n lọ pàgọ́ sí Etamu tí ó wà létí aṣálẹ̀. 7Láti ibẹ̀ wọ́n pada sẹ́yìn lọ sí Pi Hahirotu tí ó wà níwájú Baali Sefoni, wọ́n pàgọ́ siwaju Migidoli. 8Wọ́n kúrò níwájú Pi Hahirotu, wọ́n la ààrin òkun kọjá lọ sinu aṣálẹ̀. Lẹ́yìn ìrìn ọjọ́ mẹta ninu aṣálẹ̀ Etamu, wọ́n pàgọ́ sí Mara. 9Wọ́n kúrò ní Mara, wọ́n lọ pàgọ́ sí Elimu níbi tí orísun omi mejila ati aadọrin igi ọ̀pẹ wà.
10Wọ́n kúrò ní Elimu, wọ́n lọ pàgọ́ sí etí Òkun Pupa. 11Wọ́n kúrò níbẹ̀, wọ́n lọ pàgọ́ sí aṣálẹ̀ Sini. 12Wọ́n kúrò ní aṣálẹ̀ Sini, wọ́n lọ pàgọ́ sí Dofika. 13Wọ́n kúrò ní Dofika, wọ́n lọ pàgọ́ sí Aluṣi. 14Wọ́n kúrò ní Aluṣi, wọ́n lọ pàgọ́ sí Refidimu níbi tí wọn kò ti rí omi mu.
15Wọ́n kúrò ní Refidimu lọ sí aṣálẹ̀ Sinai. 16Láti aṣálẹ̀ Sinai wọ́n lọ sí Kiburotu Hataafa. 17Láti Kiburotu Hataafa wọ́n lọ sí Haserotu. 18Láti Haserotu wọ́n lọ sí Ritima. 19Láti Ritima wọ́n lọ sí Rimoni Peresi. 20Láti Rimoni Peresi wọ́n lọ sí Libina. 21Láti Libina wọ́n lọ sí Risa. 22Láti Risa wọ́n lọ sí Kehelata. 23Láti Kehelata wọ́n lọ sí Òkè Ṣeferi. 24Láti Òkè Ṣeferi wọ́n lọ sí Harada. 25Láti Harada wọ́n lọ sí Makihelotu. 26Láti Makihelotu wọ́n lọ sí Tahati. 27Láti Tahati wọ́n lọ sí Tẹra. 28Láti Tẹra wọ́n lọ sí Mitika. 29Láti Mitika wọ́n lọ sí Haṣimona. 30Láti Haṣimona wọ́n lọ sí Moserotu. 31Láti Moserotu wọ́n lọ sí Bene Jaakani. 32Láti Bene Jaakani wọ́n lọ sí Hori Hagidigadi. 33Láti Hori Hagidigadi wọ́n lọ sí Jotibata. 34Láti Jotibata wọ́n lọ sí Abirona. 35Láti Abirona wọ́n lọ sí Esiongeberi. 36Láti Esiongeberi wọ́n lọ sí aṣálẹ̀ Sini, tíí ṣe Kadeṣi. 37Láti Kadeṣi wọ́n lọ sí Òkè Hori, lẹ́bàá ilẹ̀ Edomu.
38Aaroni alufaa gun Òkè Hori lọ bí OLUWA ti pa á láṣẹ fún un, níbẹ̀ ni ó sì kú sí ní ọjọ́ kinni oṣù karun-un, ogoji ọdún lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní Ijipti. 39Aaroni jẹ́ ẹni ọdún mẹtalelọgọfa (123) nígbà tí ó kú ní Òkè Hori.#Nọm 20:22-28; Diut 10:6; 32:50
40Ọba ìlú Aradi, ní ilẹ̀ Kenaani, tí ń gbé Nẹgẹbu gbúròó pé àwọn ọmọ Israẹli ń bọ̀.#Nọm 21:1
41Wọ́n kúrò ní Òkè Hori wọn lọ sí Salimona. 42Wọ́n kúrò ní Salimona wọ́n lọ sí Punoni. 43Láti Punoni wọ́n lọ sí Obotu. 44Láti Obotu wọ́n lọ sí Òkè Abarimu ní agbègbè Moabu. 45Láti Iyimu wọ́n lọ sí Diboni Gadi. 46Láti Diboni Gadi wọ́n lọ sí Alimoni Dibilataimu. 47Láti Alimoni Dibilataimu wọ́n lọ sí Òkè Abarimu níwájú Nebo. 48Láti Òkè Abarimu wọ́n lọ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu lẹ́bàá odò Jọdani létí Jẹriko. 49Wọ́n sì pàgọ́ wọn sí ẹ̀bá odò Jọdani láti Beti Jeṣimotu títí dé Abeli Ṣitimu ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu.
Ìlànà Nípa Líla Odò Jọdani Kọjá
50OLUWA sọ fún Mose ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu lẹ́bàá odò Jọdani létí Jẹriko pé 51kí ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Nígbà tí ẹ bá ré odò Jọdani kọjá sí ilẹ̀ Kenaani, 52ẹ gbọdọ̀ lé gbogbo àwọn eniyan tí ń gbé ilẹ̀ náà kúrò. Ẹ run gbogbo àwọn oriṣa tí wọ́n fi òkúta ati irin ṣe ati gbogbo ilé oriṣa wọn. 53Kí ẹ gba ilẹ̀ náà kí ẹ sì máa gbé inú rẹ̀, nítorí pé mo ti fun yín gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní yín. 54Gègé ni kí ẹ fi pín ilẹ̀ náà fún àwọn ẹ̀yà Israẹli. Fún àwọn tí ó pọ̀ ní ilẹ̀ pupọ, sì fún àwọn tí ó kéré ní ilẹ̀ kékeré. Ilẹ̀ tí gègé olukuluku bá mú ni yóo jẹ́ tirẹ̀, láàrin àwọn ẹ̀yà yín ni ẹ óo ti pín ilẹ̀ náà. 55Ṣugbọn bí ẹ kò bá lé gbogbo àwọn ará ilẹ̀ náà kúrò, àwọn tí ó bá kù yóo di ẹ̀gún ní ojú yín ati ẹ̀gún ní ìhà yín, wọn yóo sì máa yọ yín lẹ́nu lórí ilẹ̀ náà. 56Bí ẹ kò bá lé gbogbo wọn jáde, ohun tí mo ti pinnu láti ṣe sí wọn, ẹ̀yin ni n óo ṣe é sí.”#Nọm 26:54-56.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

NỌMBA 33: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀