NỌMBA 34

34
Àwọn Ààlà Ilẹ̀ náà
1OLUWA sọ fún Mose pé, 2“Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ Kenaani tí mo fun yín, gbogbo ilẹ̀ náà ni yóo jẹ́ tiyín. Àwọn ààlà ilẹ̀ yín nìwọ̀nyí.’ 3Ilẹ̀ yín ní ìhà gúsù yóo bẹ̀rẹ̀ láti aṣálẹ̀ Sini lẹ́bàá ààlà Edomu. Ààlà yín ní ìhà gúsù yóo jẹ́ láti òpin Òkun-Iyọ̀ ní ìlà oòrùn. 4Yóo sì yí láti ìhà gúsù lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Akirabimu, yóo sì la aṣálẹ̀ Sini kọjá lọ títí dé ìhà gúsù Kadeṣi Banea ati títí dé Hasari Adari ati títí dé Asimoni. 5Yóo sì yí láti Asimoni lọ dé odò Ijipti, òkun ni yóo sì jẹ́ òpin rẹ̀.
6“Ní ìhà ìwọ̀ oòrùn Òkun ni yóo jẹ́ ààlà yín.
7“Ní ìhà àríwá, ààlà yín yóo gba ẹ̀gbẹ́ òkun ńlá lọ títí dé Òkè Hori. 8Láti ibẹ̀ lọ dé ẹnu ibodè Hamati, títí dé Sedadi, 9Sifironi ati Hasari Enani.
10“Ààlà ìhà ìlà oòrùn yín yóo gba ẹ̀gbẹ́ Hasari Enani lọ sí Ṣefamu. 11Yóo lọ sí ìhà gúsù sí Ribila ní ìhà ìlà oòrùn Aini títí lọ sí àwọn òkè tí wọ́n wà létí ìhà ìlà oòrùn Òkun-Kinereti. 12Láti ibẹ̀ lọ sí ìhà gúsù lẹ́bàá odò Jọdani, yóo parí sí Òkun-Iyọ̀. Àwọn ni yóo jẹ́ ààlà ilẹ̀ yín.”
13Mose sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Èyí ni ilẹ̀ tí ẹ óo fi gègé pín. Ilẹ̀ tí OLUWA yóo fún àwọn ẹ̀yà mẹsan-an ààbọ̀ yòókù. #Nọm 26:52-56. 14Àwọn ẹ̀yà Reubẹni ati ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase ti gba ilẹ̀ tiwọn, tí a pín gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn. 15ní ìhà ìlà oòrùn Jọdani ní òdìkejì Jẹriko. Wọ́n sì ti pín in ní ìdílé-ìdílé.” #Joṣ 14:1-5.
Àwọn Olórí tí Yóo Pín Ilẹ̀ náà
16OLUWA sọ fún Mose pé, 17“Eleasari alufaa ati Joṣua ọmọ Nuni ni yóo pín ilẹ̀ náà fun yín. 18Mú olórí kọ̀ọ̀kan ninu ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan láti ràn wọ́n lọ́wọ́.” 19Àwọn olórí náà nìwọ̀nyí: láti inú ẹ̀yà Juda, a yan Kalebu ọmọ Jefune. 20Láti inú ẹ̀yà Simeoni, a yan Ṣemueli ọmọ Amihudu. 21Láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini, a yan Elidadi ọmọ Kisiloni. 22Láti inú ẹ̀yà Dani, a yan Buki ọmọ Jogili. 23Láti inú ẹ̀yà Manase, a yan Hanieli ọmọ Efodu. 24Láti inú ẹ̀yà Efuraimu, a yan Kemueli ọmọ Ṣifitani. 25Láti inú ẹ̀yà Sebuluni, a yan Elisafani ọmọ Parinaki. 26Láti inú ẹ̀yà Isakari, a yan Palitieli ọmọ Asani. 27Láti inú ẹ̀yà Aṣeri, a yan Ahihudu ọmọ Ṣelomi. 28Láti inú ẹ̀yà Nafutali, a yan Pedaheli ọmọ Amihudu.
29Àwọn ni OLUWA pàṣẹ fún láti pín ilẹ̀ ìní náà fún àwọn ọmọ Israẹli ní ilẹ̀ Kenaani.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

NỌMBA 34: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀