NỌMBA 35
35
Àwọn Ìlú tí A Fún Àwọn Ọmọ Lefi
1Ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu ní ìhà ìlà oòrùn Jọdani ní òdìkejì Jẹriko, OLUWA sọ fún Mose pé, 2“Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli pé ninu ilẹ̀ ìní wọn, kí wọ́n fún àwọn ọmọ Lefi ní àwọn ìlú tí wọn yóo máa gbé, kí wọ́n sì fún wọn ní ilẹ̀ pápá yíká àwọn ìlú wọnyi. 3Àwọn ìlú náà yóo jẹ́ ti àwọn ọmọ Lefi, wọn óo máa gbébẹ̀. Ilẹ̀ tí ó yí àwọn ìlú náà ká yóo wà fún àwọn ẹran ọ̀sìn wọn ati mààlúù wọn. 4Kí ilẹ̀ pápá tí yóo yí àwọn ìlú tí ẹ óo fún àwọn ọmọ Lefi ká jẹ́ ẹgbẹrun igbọnwọ láti ibi odi ìlú wọn siwaju. 5Lẹ́yìn odi ìlú kọ̀ọ̀kan, kí ẹ wọn ẹgbaa igbọnwọ ní ìhà kọ̀ọ̀kan ní ìhà ìlà oòrùn, ati ìhà gúsù, ati ìhà ìwọ̀ oòrùn, ati ìhà àríwá; kí ìlú wà ní ààrin. Ilẹ̀ tí ẹ wọ̀n yìí ni yóo jẹ́ ibùjẹ fún àwọn ẹran ọ̀sìn. 6Ninu àwọn ìlú tí ẹ óo fún àwọn ọmọ Lefi, mẹfa ninu wọn yóo jẹ́ ìlú ààbò tí ẹni tí ó bá ṣèèṣì paniyan lè sá lọ. Lẹ́yìn ìlú mẹfa yìí, ẹ óo tún fún wọn ní ìlú mejilelogoji pẹlu ilẹ̀ tí ó yí wọn ká. 7Gbogbo ìlú tí ẹ óo fún wọn yóo jẹ́ mejidinlaadọta pẹlu ilẹ̀ pápá tí ó yí wọn ká. 8Bí ilẹ̀ ìní olukuluku ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli bá ti tóbi tó, bẹ́ẹ̀ ni iye ìlú tí wọn yóo fi sílẹ̀ fún àwọn ọmọ Lefi yóo pọ̀ tó.” #Joṣ 21:1-42
Àwọn Ìlú-Ààbò
(Diut 19:1-13; Joṣ 20:1-9)
9OLUWA sọ fún Mose pé, 10“Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, nígbà tí wọ́n bá ré Jọdani kọjá sí ilẹ̀ Kenaani, 11kí wọ́n yan ìlú mẹfa fún ìlú ààbò tí ẹni tí ó bá ṣèèṣì paniyan lè sá lọ. 12Yóo jẹ́ ibi ààbò fún ẹni tí ó paniyan, bí arakunrin ẹni tí ó pa bá fẹ́ gbẹ̀san, nítorí pé ẹ kò gbọdọ̀ pa ẹni tí ó bá ṣèèṣì paniyan títí yóo fi dúró níwájú ìjọ eniyan Israẹli fún ìdájọ́. 13Ẹ óo yan ìlú mẹfa fún èyí. 14Mẹta ní ìhà ìlà oòrùn odò Jọdani ati mẹta ní ilẹ̀ Kenaani. 15Wọn yóo jẹ́ ìlú ààbò fún àwọn ọmọ Israẹli tabi àwọn àlejò tí ó wà láàrin wọn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣèèṣì paniyan lè sá lọ sibẹ.
16“Ṣugbọn bí ẹnìkan bá fi ohun èlò irin lu arakunrin rẹ̀ tí ẹni náà sì kú, apànìyàn ni ẹni tí ó fi ohun èlò irin lu arakunrin rẹ̀, pípa ni wọn yóo pa òun náà. 17Bí ó bá sọ òkúta lu arakunrin rẹ̀ tí arakunrin náà sì kú, apànìyàn ni; pípa ni wọn yóo pa òun náà. 18Tabi tí ó bá fi ohun ìjà olóró lu arakunrin rẹ̀ tí ẹni náà sì kú, apànìyàn ni, pípa ni wọn yóo pa òun náà. 19Arakunrin ẹni tí a pa ni yóo pa apànìyàn náà nígbà tí ó bá rí i.
20“Bí ẹnìkan bá kórìíra arakunrin rẹ̀, tí ó sì fi ohun ìjà gún un, tabi tí ó ju nǹkan lù ú láti ibi tí ó sápamọ́ sí, tí ẹni náà bá kú, 21tabi tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ lù ú pẹlu ibinu tí ẹni náà sì kú. Apànìyàn náà yóo jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ìpànìyàn, yóo sì kú fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Arakunrin ẹni tí ó pa ni yóo pa apànìyàn náà nígbà tí ó bá rí i.
22“Ṣugbọn bí ẹnìkan bá ṣèèṣì paniyan, tí kì í ṣe pẹlu ìríra, kì báà jẹ́ pé ó fi ohun ìjà gún un, tabi kí ó ṣèèṣì ju nǹkan lù ú, 23tabi bí ẹnìkan bá ṣèèṣì sọ òkúta láì wo ibi tí ó sọ òkúta náà sí, tí òkúta náà sì pa eniyan tí kì í ṣe pé ó ti fẹ́ pa olúwarẹ̀ tẹ́lẹ̀, tí kò sì kórìíra rẹ̀, 24kí ìjọ eniyan Israẹli ṣe ìdájọ́ láàrin ẹni tí ó ṣèèṣì paniyan ati arakunrin ẹni tí wọ́n pa, tí ó fẹ́ gbẹ̀san, gẹ́gẹ́ bí ìlànà yìí. 25Kí ìjọ eniyan gba ẹni tí ó paniyan náà lọ́wọ́ olùgbẹ̀san, kí wọ́n mú un pada lọ sí ìlú ààbò rẹ̀. Níbẹ̀ ni yóo sì máa gbé títí tí olórí alufaa tí a fi òróró yàn yóo fi kú. 26Ṣugbọn bí apànìyàn náà bá rékọjá odi ìlú ààbò rẹ̀, 27tí arakunrin ẹni tí ó pa bá rí i tí ó sì pa á, olùgbẹ̀san náà kì yóo ní ẹ̀bi; 28nítorí pé apànìyàn náà gbọdọ̀ dúró ní ìlú ààbò rẹ̀ títí tí olórí alufaa yóo fi kú, lẹ́yìn náà, ó lè pada sí ilẹ̀ ìní rẹ̀. #Diut 19:24; Joṣ 20:1-9 29Èyí yóo jẹ́ ìlànà ati òfin fun yín láti ìrandíran yín níbikíbi tí ẹ bá ń gbé.
30“Kí ẹ tó pa ẹnikẹ́ni tí ó bá paniyan, ẹlẹ́rìí meji gbọdọ̀ jẹ́rìí sí i pé nítòótọ́ ni olúwarẹ̀ paniyan. Ẹ̀rí eniyan kan kò tó fún ẹjọ́ apànìyàn. 31Kí ẹ má ṣe gba owó ìtanràn lọ́wọ́ ẹni tí ó jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ìpànìyàn, pípa ni ẹ gbọdọ̀ pa òun náà. 32Bí apànìyàn kan bá sá lọ sí ìlú ààbò, ẹ kò gbọdọ̀ gba owó ìtanràn lọ́wọ́ rẹ̀, kí ó baà lè pada sí ilẹ̀ ìní rẹ̀ ṣáájú ikú olórí alufaa. 33Bí ẹ bá ṣe èyí, ẹ óo sọ ilẹ̀ yín di aláìmọ́ nítorí pé ìpànìyàn a máa sọ ilẹ̀ di àìmọ́. Ikú apànìyàn nìkan ni ó sì lè ṣe ètùtù fún ìwẹ̀nùmọ́ ilẹ̀ tí ó ti di àìmọ́ nípa ìpànìyàn. 34Ẹ má ṣe sọ ilẹ̀ tí ẹ̀ ń gbé di aláìmọ́, àní, ilẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli láàrin àwọn tí èmi OLUWA ń gbé.” #Diut 17:6; 19:15
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
NỌMBA 35: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010