NỌMBA 36

36
Ogún Àwọn Obinrin Abilékọ
1Àwọn olórí ìdílé àwọn ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri ati ẹ̀yà Manase ọmọ Josẹfu, wá sọ́dọ̀ Mose ati àwọn olórí ẹ̀yà Israẹli, 2wọ́n ní, “OLUWA pàṣẹ fun yín pé kí ẹ fi gègé pín ilẹ̀ náà fún àwọn eniyan Israẹli. Ó sì pàṣẹ fun yín pé kí ẹ fi ilẹ̀-ìní arakunrin wa Selofehadi fún àwọn ọmọbinrin rẹ̀. 3Ṣugbọn bí wọ́n bá lọ́kọ lára ẹ̀yà Israẹli mìíràn, a ó gba ilẹ̀-ìní wọn kuro ninu ilẹ̀-ìní awọn baba wa, ilẹ̀-ìní wọn yóo jẹ́ ti ẹ̀yà àwọn ọkọ wọn, èyí yóo sì mú kí ilẹ̀ wa dínkù. 4Nígbà tí ọdún jubili bá kò, tí a óo dá gbogbo ilẹ̀-ìní pada fún àwọn tí wọ́n ni wọ́n, ilẹ̀-ìní àwọn ọmọbinrin Selofehadi yóo jẹ́ ti ẹ̀yà àwọn ọkọ wọn, èyí yóo sì mú kí ilẹ̀ tiwa dínkù.”#Nọm 27:7
5Mose bá pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti wí fún un, pé, “Ohun tí ẹ̀yà Manase sọ dára, 6nítorí náà OLUWA wí pé àwọn ọmọbinrin Selofehadi ní ẹ̀tọ́ láti fẹ́ ẹnikẹ́ni tí ó wù wọ́n, ṣugbọn ó gbọdọ̀ jẹ́ láti inú ẹ̀yà wọn. 7Ilẹ̀-ìní ẹ̀yà kan kò gbọdọ̀ di ti ẹ̀yà mìíràn, ilẹ̀ ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ wà ní ìkáwọ́ rẹ̀. 8Obinrin tí ó bá ní ilẹ̀-ìní gbọdọ̀ fẹ́ ọkọ láàrin ẹ̀yà rẹ̀, kí olukuluku àwọn ọmọ Israẹli lè máa jogún ilẹ̀ ìní baba rẹ̀.” 9Ilẹ̀-ìní ẹ̀yà kan kò gbọdọ̀ di ti ẹ̀yà mìíràn, ilẹ̀ ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ wà ní ìkáwọ́ rẹ̀.
10Àwọn ọmọbinrin Selofehadi ṣe gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA fún Mose; 11Mahila, Tirisa, Hogila, Milika ati Noa fẹ́ ọkọ láàrin àwọn arakunrin baba wọn, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ. 12Wọ́n fẹ́ ọkọ láàrin ẹ̀yà Manase ọmọ Josẹfu, ilẹ̀-ìní wọn sì dúró ninu ẹ̀yà baba wọn.
13Àwọn ni ìlànà ati òfin tí OLUWA ti pa láṣẹ fún Mose fún àwọn ọmọ Israẹli, ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu ní ìhà ìlà oòrùn Jọdani, ní òdìkejì Jẹriko.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

NỌMBA 36: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa