NỌMBA 32

32
Àwọn Ẹ̀yà Ìlà Oòrùn Jọdani
(Diut 3:12-22)
1Nígbà tí àwọn ọmọ Reubẹni ati àwọn ọmọ Gadi, tí wọ́n ní ẹran ọ̀sìn pupọ, rí ilẹ̀ Jaseri ati ilẹ̀ Gileadi pé ibẹ̀ dára fún àwọn ẹran ọ̀sìn wọn, 2wọ́n wá siwaju Mose, ati Eleasari ati àwọn olórí àwọn eniyan, wọ́n ní, 3“Atarotu ati Diboni ati Jaseri ati Nimra ati Heṣiboni ati Eleale ati Sebamu ati Nebo ati Beoni, 4tí OLUWA ti ran àwọn ọmọ Israẹli lọ́wọ́ láti gbà jẹ́ ilẹ̀ tí ó dára fún ẹran ọ̀sìn, àwa iranṣẹ yín sì ní ẹran ọ̀sìn pupọ. 5Nítorí náà, àwa bẹ̀ yín, ẹ fún wa ní ilẹ̀ yìí gẹ́gẹ́ bí ìní wa, ẹ má kó wa sọdá odò Jọdani.”
6Mose bá dá wọn lóhùn, ó ní, “Ṣé ẹ fẹ́ jókòó níhìn-ín kí àwọn arakunrin yín máa lọ jagun ni? 7Kí ló dé tí ẹ fi mú ọkàn àwọn ọmọ Israẹli rẹ̀wẹ̀sì kí wọ́n má baà rékọjá lọ sinu ilẹ̀ tí OLUWA fi fún wọn? 8Bẹ́ẹ̀ ni àwọn baba yín ṣe nígbà tí mo rán wọn láti Kadeṣi Banea láti lọ ṣe amí ilẹ̀ náà. 9Wọ́n lọ títí dé àfonífojì Eṣikolu, wọ́n wo ilẹ̀ náà. Ṣugbọn nígbà tí wọ́n pada dé, wọ́n mú kí ọkàn àwọn ọmọ Israẹli rẹ̀wẹ̀sì, kí wọn má lè lọ sí ilẹ̀ tí OLUWA ti fi fún wọn.#Nọm 13:17-33 10Nítorí náà ni ibinu Ọlọrun ṣe ru sí wọn nígbà náà. Ó sì búra pé, 11‘Ọ̀kan ninu àwọn tí ó ti ilẹ̀ Ijipti wá, láti ẹni ogún ọdún sókè kò ní rí ilẹ̀ náà tí mo ṣèlérí fún Abrahamu, fún Isaaki ati fún Jakọbu, nítorí pé wọn kò fi tọkàntọkàn ṣe tèmi.’ 12Àfi Kalebu ọmọ Jefune, ọmọ Kenisi ati Joṣua ọmọ Nuni, nítorí pé wọ́n fi tọkàntọkàn ṣe tèmi. 13Ibinu OLUWA ru sí àwọn ọmọ Israẹli, ó sì mú wọn rìn kiri ninu aṣálẹ̀ fún ogoji ọdún títí gbogbo àwọn tí wọ́n ṣe burúkú níwájú OLUWA fi kú tán. 14Nisinsinyii, ẹ̀yin ìran ẹlẹ́ṣẹ̀ yìí dìde gẹ́gẹ́ bí àwọn baba ńlá yín láti mú kí inú bí OLUWA gidigidi sí Israẹli. 15Bí ẹ̀yin ẹ̀yà Reubẹni ati ẹ̀yà Gadi bá pada lẹ́yìn OLUWA, yóo kọ àwọn eniyan wọnyi sílẹ̀ sinu aṣálẹ̀. A jẹ́ pé ẹ̀yin ni ẹ fa ìparun wọn.”#Nọm 14:26-35
16Wọ́n dá Mose lóhùn pé, “A óo kọ́ ilé fún àwọn ẹran ọ̀sìn wa níhìn-ín ati ìlú olódi fún àwọn ọmọ wa. 17Ṣugbọn àwa tìkarawa yóo di ihamọra ogun wa, a óo sì ṣáájú ogun fún àwọn yòókù títí wọn yóo fi gba ilẹ̀ ìní tiwọn. Ṣugbọn àwọn ọmọ wa yóo máa gbé ninu ìlú olódi níhìn-ín kí àwọn eniyan ilẹ̀ náà má baà yọ wọ́n lẹ́nu. 18A kò ní pada sí ilẹ̀ wa títí olukuluku àwọn ọmọ Israẹli yóo fi ní ilẹ̀ ìní tirẹ̀. 19A kò ní bá wọn pín ninu ilẹ̀ òdìkejì odò Jọdani nítorí pé a ti ní ilẹ̀ ìní tiwa ní ìhà ìlà oòrùn odò Jọdani níhìn-ín.”
20Mose bá dá wọn lóhùn, ó ní, “Bí nǹkan tí ẹ sọ yìí bá ti ọkàn yín wá, tí ẹ bá di ihamọra ogun yín níwájú OLUWA, 21tí àwọn ọmọ ogun yín sì ṣetán láti ré odò Jọdani kọjá ní àṣẹ OLUWA láti gbógun ti àwọn ọ̀tá wa títí OLUWA yóo fi pa wọ́n run, 22tí yóo sì gba ilẹ̀ náà, lẹ́yìn náà, ẹ lè pada nítorí pé ẹ ti ṣe ẹ̀tọ́ yín sí OLUWA ati sí àwọn arakunrin yín. Ilẹ̀ yìí yóo sì máa jẹ́ ìní yín pẹlu àṣẹ OLUWA. 23Ṣugbọn bí ẹ kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA. Ẹ jẹ́ kí ó da yín lójú pé ẹ kò ní lọ láì jìyà ẹ̀ṣẹ̀ yín. 24Ẹ lọ kọ́ àwọn ìlú fún àwọn ọmọ yín ati ilé fún àwọn ẹran ọ̀sìn yín, kí ẹ sì ṣe ohun tí ẹ ṣèlérí.”
25Àwọn ọmọ Reubẹni ati Gadi sì dá Mose lóhùn, wọ́n ní, 26“Àwọn ọmọ wa, àwọn aya wa, àwọn mààlúù wa ati aguntan wa yóo wà ní àwọn ìlú Gileadi, 27ṣugbọn a ti ṣetán láti lọ sí ojú ogun nípa àṣẹ OLUWA. A óo ré odò Jọdani kọjá láti jagun gẹ́gẹ́ bí o ti sọ.”
28Mose bá pàṣẹ fún Eleasari alufaa, ati fún Joṣua ọmọ Nuni ati fún àwọn olórí àwọn ẹ̀yà Israẹli nípa wọn, ó ní, 29“Bí àwọn ọmọ Reubẹni ati Gadi bá bá yín ré odò Jọdani kọjá láti jagun níwájú OLUWA, bí wọ́n bá sì ràn yín lọ́wọ́ láti gba ilẹ̀ náà, ẹ óo fún wọn ní ilẹ̀ Gileadi gẹ́gẹ́ bí ìní wọn. 30Ṣugbọn bí wọn kò bá bá yín ré odò Jọdani kọjá, tí wọn kò sì lọ sí ojú ogun pẹlu yín, wọn óo gba ìpín ilẹ̀ ìní tiwọn ní Kenaani bíi àwọn ọmọ Israẹli yòókù.”
31Àwọn ọmọ Gadi ati àwọn ọmọ Reubẹni dáhùn, wọ́n ní, “A óo ṣe ohun tí OLUWA bá pa láṣẹ. 32Nípa àṣẹ rẹ̀ ni a óo ré odò Jọdani kọjá, a óo lọ jagun ní ilẹ̀ Kenaani, kí ilẹ̀ ìhà ìlà oòrùn Jọdani lè jẹ́ tiwa.”#Joṣ 1:12-15
33Mose bá fi ilẹ̀ Sihoni, ọba àwọn ará Amori, ilẹ̀ Ogu, ọba Baṣani ati àwọn ilẹ̀ ati àwọn ìlú tí ó yí wọn ká fún àwọn ọmọ Gadi, àwọn ọmọ Reubẹni ati ìdajì ẹ̀yà Manase ọmọ Josẹfu. 34Àwọn ọmọ Gadi sì tún àwọn ìlú olódi wọnyi kọ́: Diboni, Atarotu ati Aroeri, 35ati Atirotu Ṣofani, Jaseri, Jogibeha, 36ati Beti Nimra, Beti Harani, àwọn ìlú olódi ati ilé fún àwọn aguntan. 37Àwọn ọmọ Reubẹni tún àwọn ìlú wọnyi kọ́: Heṣiboni, Eleale, Kiriataimu, 38Nebo, Baali Meoni (wọ́n yí orúkọ ìlú yìí pada) ati Sibima. Wọ́n sì fún àwọn ìlú tí wọn tún kọ́ ní orúkọ mìíràn.
39Àwọn ọmọ Makiri tíí ṣe ẹ̀yà Manase gbógun ti àwọn ará Amori tí ó wà ní Gileadi, wọ́n lé wọn jáde, wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn. 40Nítorí náà Mose fi ilẹ̀ Gileadi fún àwọn ọmọ Makiri láti inú ẹ̀yà Manase, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀. 41Jairi ọmọ Manase gbógun ti àwọn ìlú kan, ó sì gbà wọ́n. Ó sọ orúkọ wọn ní Hafoti Jairi. 42Noba gbógun ti Kenati ati àwọn ìletò rẹ̀, ó sì gbà wọ́n. Ó sọ orúkọ rẹ̀ ní Noba tíí ṣe orúkọ ara rẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

NỌMBA 32: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀