Wọ̀nyí ni ìrìnàjò àwọn ọmọ Israẹli ní ẹsẹẹsẹ, nígbà tí wọ́n tí ilẹ̀ Ejibiti jáde wá pẹ̀lú àwọn ogun wọn, nípa ọwọ́ Mose àti Aaroni. Mose sì kọ̀wé ìjáde lọ wọn ní ẹsẹẹsẹ gẹ́gẹ́ bí ìrìnàjò wọn, nípa àṣẹ OLúWA; Wọ̀nyí sì ni ìrìnàjò wọn gẹ́gẹ́ bí ìjáde lọ wọn. Àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò láti Ramesesi ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù kìn-ín-ní, ọjọ́ kan lẹ́yìn àjọ Ìrékọjá. Wọ́n yan jáde pẹ̀lú ìgboyà níwájú gbogbo àwọn ará Ejibiti. Tí wọ́n sì ń sin gbogbo àkọ́bí wọn, ẹni tí OLúWA ti gbé lulẹ̀ láàrín wọn; nítorí tí OLúWA ti mú ẹ̀san wá sórí àwọn òrìṣà wọn. Àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní Ramesesi wọ́n sì pàgọ́ sí Sukkoti. Wọ́n kúrò ní Sukkoti, wọ́n sì pàgọ́ sí Etamu, ní ẹ̀bá aginjù. Wọ́n kúrò ní Etamu, wọ́n padà sí Pi-Hahirotu sí ìlà-oòrùn Baali-Ṣefoni, wọ́n sì pàgọ́ sí ẹ̀bá Migdoli. Wọ́n sì dìde láti lọ kúrò ní iwájú Pi-Hahirotu, wọ́n sì la àárín Òkun kọjá lọ sí aginjù: Wọ́n sì rin ìrìn ọjọ́ mẹ́ta ní aginjù Etamu, wọ́n sì pàgọ́ sí Mara. Wọ́n kúrò ní Mara wọ́n sì lọ sí Elimu, níbi tí orísun omi méjìlá (12) àti igi ọ̀pẹ àádọ́rin (70) gbé wà, wọ́n sì pàgọ́ níbẹ̀. Wọ́n kúrò ní Elimu wọ́n sì pàgọ́ sí ẹ̀bá Òkun Pupa. Wọ́n kúrò ní ẹ̀bá Òkun Pupa wọ́n sì pàgọ́ sínú aginjù Sini. Wọ́n kúrò nínú aginjù Sini wọ́n sì pàgọ́ sí aginjù Dofka. Wọ́n kúrò ní Dofka wọ́n sì pàgọ́ ní Aluṣi. Wọ́n kúrò ní Aluṣi wọ́n sì pàgọ́ ní Refidimu níbi tí kò sí omi fún àwọn ènìyàn náà láti mu. Wọ́n kúrò ní Refidimu wọ́n sì pàgọ́ ní aginjù Sinai. Wọ́n kúrò ní aginjù Sinai wọ́n sì pàgọ́ ní Kibirotu-Hattaafa. Wọ́n kúrò ní Kibirotu-Hattaafa wọ́n sì pàgọ́ ní Haserotu. Wọ́n kúrò ní Haserotu wọ́n sì pàgọ́ ní Ritma. Wọ́n kúrò ní Ritma wọ́n sì pàgọ́ ní Rimoni-Peresi. Wọ́n kúrò ní Rimoni-Peresi wọ́n sì pàgọ́ ní Libina. Wọ́n kúrò ní Libina wọ́n sì pàgọ́ ní Rissa. Wọ́n kúrò ní Rissa wọ́n sì pàgọ́ ní Kehelata. Wọ́n kúrò ní Kehelata wọ́n sì pàgọ́ ní orí òkè Ṣeferi. Wọ́n kúrò lórí òkè Ṣeferi wọ́n sì pàgọ́ ní Harada. Wọ́n kúrò ní Harada wọ́n sì pàgọ́ ní Makhelotu. Wọ́n kúrò ní Makhelotu wọ́n sì pàgọ́ ní Tahati. Wọ́n kúrò ní Tahati wọ́n sì pàgọ́ ní Tẹra. Wọ́n kúrò ní Tẹra wọ́n sì pàgọ́ ní Mitka. Wọ́n kúrò ní Mitka wọ́n pàgọ́ ní Haṣmona. Wọ́n kúrò ní Haṣmona wọ́n sì pàgọ́ ní Moserotu. Wọ́n kúrò ní Moserotu wọ́n sì pàgọ́ ní Bene-Jaakani. Wọ́n kúrò ní Bene-Jaakani wọ́n sì pàgọ́ ní Hori-Haggidgadi. Wọ́n kúrò ní Hori-Haggidgadi wọ́n sí pàgọ́ ní Jotbata. Wọ́n kúrò ní Jotbata wọ́n sì pàgọ́ ní Abrona. Wọ́n kúrò ní Abrona wọ́n sì pàgọ́ ní Esioni-Geberi. Wọ́n kúrò ní Esioni-Geberi wọ́n sì pàgọ́ ní Kadeṣi nínú aginjù Sini. Wọ́n kúrò ní Kadeṣi wọ́n sì pàgọ́ ní orí òkè Hori, lẹ́bàá Edomu. Nípa àṣẹ OLúWA, Aaroni àlùfáà gùn orí òkè Hori, níbẹ̀ ni ó kú. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù karùn-ún, ọdún ogójì, lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Israẹli ti ilẹ̀ Ejibiti jáde wá. Aaroni jẹ́ ẹni ọgọ́fà ọdún ó-lé-mẹ́ta ní ìgbà tí ó kú sí orí òkè Hori.
Kà Numeri 33
Feti si Numeri 33
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Numeri 33:1-39
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò