ẸKÚN JEREMAYA 3:19-24

ẸKÚN JEREMAYA 3:19-24 YCE

Ranti ìyà ati ìbànújẹ́ mi, ati ìrora ọkàn mi! Mò ń ranti nígbà gbogbo, ọkàn mi sì ń rẹ̀wẹ̀sì. Ṣugbọn mo tún ń ranti nǹkankan, mo sì ní ìrètí. Nítorí pé Ìfẹ́ OLUWA tí kì í yẹ̀ kò nípẹ̀kun, àánú rẹ̀ kò sì lópin; ọ̀tun ni wọ́n láràárọ̀, òtítọ́ rẹ̀ pọ̀. Ọkàn mi wí pé, “OLUWA ni ìpín mi, nítorí náà lọ́dọ̀ rẹ̀ ni ìrètí mi wà.”