ẸKÚN JEREMAYA 3

3
Ìjìyà, Ìrònúpìwàdà ati Ìrètí
1Èmi ni mo mọ bí eniyan tií rí ìpọ́njú,
tí mo mọ bí Ọlọrun tií fi ibinu na eniyan ní pàṣán.
2Ó lé mi wọ inú òkùnkùn biribiri.
3Dájúdájú, ó ti dojú kọ mí,
ó sì bá mi jà léraléra tọ̀sán-tòru.
4Ó ti jẹ́ kí n rù kan egungun,
ó sì ti fọ́ egungun mi.
5Ó dótì mí,
ó fi ìbànújẹ́ ati ìṣẹ́ yí mi káàkiri.
6Ó fi mí sinu òkùnkùn
bí òkú tí ó ti kú láti ọjọ́ pípẹ́.
7Ó mọ odi yí mi ká,
ó sì fi ẹ̀wọ̀n wúwo dè mí,
kí n má baà lè sálọ.
8Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ké pè é fún ìrànlọ́wọ́,
sibẹsibẹ kò gbọ́ adura mi.
9Ó to òkúta gbígbẹ́ dí ọ̀nà mi,
ó mú kí ọ̀nà mí wọ́.
10Ó ba dè mí bí ẹranko ìjàkùmọ̀,
ó lúgọ bíi kinniun,
11Ó wọ́ mi kúrò lójú ọ̀nà mi,
ó fà mí ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ,
ó sì ti sọ mí di alailẹnikan.
12Ó kẹ́ ọfà, ó fa ọrun rẹ̀,
ó sì fi mí ṣe ohun ìtafàsí.
13Ó mú gbogbo ọfà
tí ó wà ninu apó rẹ̀
ó ta wọ́n mọ́ mi lọ́kàn.
14Mo wá di ẹni yẹ̀yẹ́
lọ́dọ̀ gbogbo eniyan,
ẹni tí wọ́n fi ń kọrin tọ̀sán-tòru.
15Ó mú kí ọkàn mi kún fún ìbànújẹ́,
ó fún mi ní iwọ mu ní àmuyó.
16Ó fẹnu mi gbolẹ̀,
títí yangí fi ká mi léyín;
ó gún mi mọ́lẹ̀ ninu eruku
17Ọkàn mi kò ní alaafia,
mo ti gbàgbé ohun tí ń jẹ́ ayọ̀.
18Nítorí náà, mo wí pé,
“Ògo mi ti tán,
ati gbogbo ohun tí mò ń retí lọ́dọ̀ OLUWA.”
19Ranti ìyà ati ìbànújẹ́ mi,
ati ìrora ọkàn mi!
20Mò ń ranti nígbà gbogbo,
ọkàn mi sì ń rẹ̀wẹ̀sì.
21Ṣugbọn mo tún ń ranti nǹkankan,
mo sì ní ìrètí.
22Nítorí pé Ìfẹ́ OLUWA tí kì í yẹ̀ kò nípẹ̀kun,
àánú rẹ̀ kò sì lópin;
23ọ̀tun ni wọ́n láràárọ̀,
òtítọ́ rẹ̀ pọ̀.
24Ọkàn mi wí pé, “OLUWA ni ìpín mi,
nítorí náà lọ́dọ̀ rẹ̀ ni ìrètí mi wà.”
25OLUWA a máa ṣe oore fún àwọn tí wọn dúró dè é,
tí wọn sì ń wá ojurere rẹ̀.
26Ó dára kí eniyan dúró jẹ́ẹ́, de ìgbàlà OLUWA.
27Ó dára kí eniyan foríti àjàgà ìtọ́sọ́nà ní ìgbà èwe.
28Kí ó fi ọwọ́ lẹ́rán, kí ó dákẹ́, kí ó sì máa wòye,
nítorí Ọlọrun ni ó gbé àjàgà náà kọ́ ọ lọ́rùn.
29Kí ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀,
bóyá ìrètí lè tún wà fún un.
30Kí ó kọ etí rẹ̀ sí ẹni tí ó fẹ́ gbá a létí,
kí wọ́n sì fi àbùkù kàn án.
31Nítorí OLUWA kò ní ta wá nù títí lae.
32Bí ó tilẹ̀ mú kí ìbànújẹ́ dé bá wa,
yóo ṣàánú wa, yóo tù wá ninu,
gẹ́gẹ́ bí ọpọlọpọ ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀.
33Nítorí pé kì í kàn déédé ni eniyan lára
tabi kí ó mú ìbànújẹ́ dé bá eniyan láìní ìdí.
34OLUWA kò faramọ́ pé kí á máa ni àwọn ẹlẹ́wọ̀n lára lórí ilẹ̀ ayé,
35kí á máa já ẹ̀tọ́ olódodo gbà lọ́wọ́ rẹ̀ níwájú Ọ̀gá Ògo,
36tabi kí á du eniyan ní ìdájọ́ òdodo.
37Ta ló pàṣẹ nǹkankan rí tí ó sì rí bẹ́ẹ̀,
láìjẹ́ pé OLUWA ló fi ọwọ́ sí i?
38Àbí kì í ṣe láti ẹnu Ọ̀gá Ògo
ni rere ati burúkú ti ń jáde?
39Kí ló dé tí ẹ̀dá alààyè kan yóo fi máa ráhùn
nígbà tí ó bá ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀?
40Ẹ jẹ́ kí á yẹ ara wa wò,
kí á tún ọ̀nà wa ṣe,
kí á sì yipada sí ọ̀dọ̀ OLUWA.
41Ẹ jẹ́ kí á gbé ojú wa sókè,
kí á ra ọwọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Ọlọrun ọ̀run:
42“A ti ṣẹ̀, a sì ti ṣoríkunkun,
ìwọ OLUWA kò sì tíì dáríjì wá.
43“O gbé ibinu wọ̀ bí ẹ̀wù,
ò ń lépa wa,
o sì ń pa wá láì ṣàánú wa.
44O ti fi ìkùukùu bo ara rẹ,
tóbẹ́ẹ̀ tí adura kankan kò lè kọjá sọ́dọ̀ rẹ.
45O ti sọ wá di ààtàn
ati ohun ẹ̀gbin láàrin àwọn eniyan.
46“Gbogbo àwọn ọ̀tá wa ń wẹnu sí wa lára.
47Ẹ̀rù ati ìṣubú, ìsọdahoro ati ìparun ti dé bá wa.
48Omijé ń dà pòròpòrò lójú mi,
nítorí ìparun àwọn eniyan mi.
49“Omijé yóo máa dà pòròpòrò lójú mi
láì dáwọ́ dúró, ati láìsinmi.
50Títí OLUWA yóo fi bojú wo ilẹ̀ láti ọ̀run wá,
tí yóo sì rí wa.
51Ìbànújẹ́ bá mi,
nígbà tí mo rí ibi tí ó ṣẹlẹ̀
sí àwọn ọmọbinrin ìlú mi.
52“Àwọn tí ń bá mi ṣọ̀tá láìnídìí ń dọdẹ mi
bí ìgbà tí eniyan ń dọdẹ ẹyẹ.
53Wọ́n jù mí sinu ihò láàyè,
wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ òkúta lù mí mọ́lẹ̀.
54Omi bò mí mọ́lẹ̀,
mo ní, ‘Mo ti gbé.’
55“Mo ké pe orúkọ rẹ, OLUWA, láti inú kòtò jíjìn.
56O gbọ́ ẹ̀bẹ̀ tí mò ń bẹ̀ pé,
‘Má ṣe di etí rẹ sí igbe tí mò ń ké fún ìrànlọ́wọ́.’
57O súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi nígbà tí mo pè ọ́,
o dá mi lóhùn pé, ‘Má bẹ̀rù.’
58“OLUWA, o ti gba ìjà mi jà,
o ti ra ẹ̀mí mi pada.
59O ti rí nǹkan burúkú tí wọ́n ṣe sí mi,
OLUWA, dá mi láre.
60O ti rí gbogbo ìgbẹ̀san wọn,
ati gbogbo ète wọn lórí mi.
61“O ti gbọ́ bí wọn tí ń pẹ̀gàn mi, OLUWA,
ati gbogbo ète wọn lórí mi.
62Gbogbo ọ̀rọ̀ ati èrò àwọn ọ̀tá mi sí mi:
ibi ni lojoojumọ.
63Kíyèsí i, wọn ìbáà jókòó,
wọn ìbáà dìde dúró,
èmi ni wọ́n máa fi ń kọrin.
64“O óo san ẹ̀san fún wọn, OLUWA,
gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn.
65Jẹ́ kí ojú inú wọn fọ́,
kí ègún rẹ sì wà lórí wọn.
66Fi ibinu lépa wọn, OLUWA,
sì pa wọ́n run láyé yìí.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ẸKÚN JEREMAYA 3: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀