ẸKÚN JEREMAYA 4

4
Jerusalẹmu, Lẹ́yìn Ìṣubú Rẹ̀
1Wo bí wúrà ti dọ̀tí,
tí ojúlówó wúrà sì yipada;
tí àwọn òkúta Tẹmpili mímọ́ sì fọ́nká ní gbogbo ìkóríta.
2Ẹ wo àwọn ọdọmọkunrin Sioni,
àwọn ọmọ tí wọn níye lórí bí ojúlówó wúrà,
tí a wá ń ṣe bí ìkòkò amọ̀;
àní, bí ìkòkò amọ̀ lásánlàsàn.
3Àwọn ajáko a máa fún àwọn ọmọ wọn lọ́mú.
Ṣugbọn àwọn eniyan mi ti di ìkà,
bí ògòǹgò inú aṣálẹ̀.
4Ahọ́n ọmọ ọmú lẹ̀ mọ́ òkè ẹnu rẹ̀ nítorí òùngbẹ.
Àwọn ọmọde ń tọrọ oúnjẹ,
ṣugbọn kò sí ẹni tí ó fún wọn.
5Àwọn tí wọn tí ń jẹ oúnjẹ àdídùn
di ẹni tí ń ṣa ilẹ̀ jẹ kiri ní ìgboro.
Àwọn tí wọn tí ń fi aṣọ àlàárì bora
di ẹni tí ń sùn lórí òkítì eérú.
6Ìjìyà àwọn eniyan mi pọ̀ ju ti àwọn ará Sodomu lọ,#Jẹn 19:24
Sodomu tí ó parun lójijì,
láìjẹ́ pé eniyan fi ọwọ́ kàn án.
7Àwọn olórí wọn kò ní àléébù kankan,
Ọwọ́ wọn mọ́, inú wọn funfun nini,
wọ́n dára ju egbin lọ,
ẹwà wọn sì dàbí ẹwà iyùn.
8Ṣugbọn nisinsinyii, ojú wọn dúdú ju èédú lọ,
kò sí ẹni tí ó dá wọn mọ̀ láàrin ìgboro,
awọ ara wọn ti hunjọ lórí egungun wọn,
wọ́n wá gbẹ bí igi.
9Ti àwọn tí wọ́n kú ikú ogun sàn ju àwọn tí wọ́n kú ikú ebi lọ,
àwọn tí ebi pa joró dójú ikú,
nítorí àìsí oúnjẹ ninu oko.
10Àwọn obinrin tí wọn ní ojú àánú ti fi ọwọ́ ara wọn se ọmọ wọn jẹ,#Diut 28:57; Isi 5:10
wọ́n fi ọmọ wọn ṣe oúnjẹ jẹ,
nígbà tí ìparun dé bá àwọn eniyan mi.
11OLUWA bínú gidigidi,
ó tú ibinu gbígbóná rẹ̀ jáde.
OLUWA dá iná kan ní Sioni tí ó jó ìpìlẹ̀ rẹ̀ run.
12Àwọn ọba ayé kò gbàgbọ́,
bẹ́ẹ̀ ni gbogbo aráyé kò gbà pé ó lè ṣẹlẹ̀,
pé ọ̀tá lè wọ ẹnubodè Jerusalẹmu.
13Ẹ̀ṣẹ̀ àwọn wolii rẹ̀ ló fa èyí,
ati àìdára àwọn alufaa rẹ̀,
tí wọ́n pa olódodo láàrin ìlú.
14Wọ́n ń káàkiri bí afọ́jú láàrin ìgboro,
ẹ̀jẹ̀ àwọn tí wọ́n pa sọ wọ́n di aláìmọ́
tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò lè fọwọ́ kan aṣọ wọn.
15Àwọn eniyan ń kígbe lé wọn lórí pé;
“Ẹ máa lọ! Ẹ̀yin aláìmọ́!
Ẹ máa kóra yín lọ! Ẹ má fi ọwọ́ kan nǹkankan!”
Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe di ìsáǹsá ati alárìnkiri,
nítorí àwọn eniyan ń wí láàrin gbogbo orílẹ̀-èdè pé,
“Àwọn wọnyi kò gbọdọ̀ bá wa gbé pọ̀ mọ́.”
16OLUWA fúnrarẹ̀ ti tú wọn ká,
kò sì ní náání wọn mọ́.
Kò ní bọlá fún àwọn alufaa wọn,
kò sì ní fi ojurere wo àwọn àgbààgbà.
17A wọ̀nà títí ojú wa di bàìbàì,
asán ni ìrànlọ́wọ́ tí à ń retí jásí.
A wọ̀nà títí fún ìrànlọ́wọ́
lọ́dọ̀ orílẹ̀-èdè tí kò lè gbani là.
18Àwọn eniyan ń ṣọ́ ìrìn ẹsẹ̀ wa,
tóbẹ́ẹ̀ tí a kò lè rìn gaara ní ìgboro.
Ìparun wa súnmọ́lé,
ọjọ́ ayé wa ti níye,
nítorí ìparun wa ti dé.
19Àwọn tí wọn ń lépa wa yára
ju idì tí ń fò lójú ọ̀run lọ.
Wọ́n ń lé wa lórí òkè,
wọ́n sì ba dè wá ninu aṣálẹ̀.
20Ẹ̀mí àwa ẹni àmì òróró OLUWA bọ́ sinu kòtò wọn,
OLUWA tí à ń sọ nípa rẹ̀ pé,
lábẹ́ òjìji rẹ̀ ni a óo máa gbé láàrin àwọn orílẹ̀-èdè.
21Ẹ máa yọ̀, kí inú yín sì máa dùn, ẹ̀yin ará Edomu,
tí ń gbé ilẹ̀ Usi.
Ṣugbọn ife náà yóo kọjá lọ́dọ̀ yín,
ẹ óo mu ún ní àmuyó,
ẹ óo sì tú ara yín síhòòhò.
22Ẹ ti jìyà ẹ̀ṣẹ̀ yín ní àjẹpé,
ẹ̀yin ará Sioni,
OLUWA kò ní fi yín sílẹ̀ ní ìgbèkùn mọ́.
Ṣugbọn yóo jẹ ẹ̀yin ará Edomu níyà fún ẹ̀ṣẹ̀ yín,
yóo tú àṣírí ẹ̀ṣẹ̀ yín.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ẸKÚN JEREMAYA 4: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀