Ẹkun Jeremiah 3:19-24

Ẹkun Jeremiah 3:19-24 YCB

Mo ṣe ìrántí ìpọ́njú àti ìdààmú mi, ìkorò àti ìbànújẹ́. Mo ṣèrántí wọn, ọkàn mi sì gbọgbẹ́ nínú mi. Síbẹ̀, èyí ni mo ní ní ọkàn àti nítorí náà ní mo nírètí. Nítorí ìfẹ́ OLúWA tí ó lágbára ni àwa kò fi ṣègbé, nítorí ti àánú rẹ kì í kùnà. Wọ́n jẹ́ ọ̀tún ní àárọ̀; títóbi ni òdodo rẹ̀. Mo wí fún ara mi, ìpín mi ni OLúWA; nítorí náà èmi yóò dúró dè ọ́.