Ẹk. Jer 3:19-24

Ẹk. Jer 3:19-24 YBCV

Ranti wahala mi ati inilara mi, ani ìkoro ati orõro. Lõtọ, nigbati ọkàn mi nṣe iranti wọn, o si tẹriba ninu mi. Eyi ni emi o rò li ọkàn mi, nitorina emi o ma reti. Ãnu Oluwa ni, ti awa kò parun tan, nitori irọnu-ãnu rẹ kò li opin. Ọtun ni li orowurọ; titobi ni otitọ rẹ. Oluwa ni ipin mi, bẹ̃li ọkàn mi wi; nitorina ni emi ṣe reti ninu rẹ̀.