Ẹk. Jer 3:19-24
Ẹk. Jer 3:19-24 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ranti wahala mi ati inilara mi, ani ìkoro ati orõro. Lõtọ, nigbati ọkàn mi nṣe iranti wọn, o si tẹriba ninu mi. Eyi ni emi o rò li ọkàn mi, nitorina emi o ma reti. Ãnu Oluwa ni, ti awa kò parun tan, nitori irọnu-ãnu rẹ kò li opin. Ọtun ni li orowurọ; titobi ni otitọ rẹ. Oluwa ni ipin mi, bẹ̃li ọkàn mi wi; nitorina ni emi ṣe reti ninu rẹ̀.

Ẹk. Jer 3:19-24 Yoruba Bible (YCE)
Ranti ìyà ati ìbànújẹ́ mi, ati ìrora ọkàn mi! Mò ń ranti nígbà gbogbo, ọkàn mi sì ń rẹ̀wẹ̀sì. Ṣugbọn mo tún ń ranti nǹkankan, mo sì ní ìrètí. Nítorí pé Ìfẹ́ OLUWA tí kì í yẹ̀ kò nípẹ̀kun, àánú rẹ̀ kò sì lópin; ọ̀tun ni wọ́n láràárọ̀, òtítọ́ rẹ̀ pọ̀. Ọkàn mi wí pé, “OLUWA ni ìpín mi, nítorí náà lọ́dọ̀ rẹ̀ ni ìrètí mi wà.”
Ẹk. Jer 3:19-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Mo ṣe ìrántí ìpọ́njú àti ìdààmú mi, ìkorò àti ìbànújẹ́. Mo ṣèrántí wọn, ọkàn mi sì gbọgbẹ́ nínú mi. Síbẹ̀, èyí ni mo ní ní ọkàn àti nítorí náà ní mo nírètí. Nítorí ìfẹ́ OLúWA tí ó lágbára ni àwa kò fi ṣègbé, nítorí ti àánú rẹ kì í kùnà. Wọ́n jẹ́ ọ̀tún ní àárọ̀; títóbi ni òdodo rẹ̀. Mo wí fún ara mi, ìpín mi ni OLúWA; nítorí náà èmi yóò dúró dè ọ́.