JOṢUA 5:13-14

JOṢUA 5:13-14 YCE

Nígbà tí Joṣua súnmọ́ ìlú Jẹriko, ó gbé ojú sókè, ó sì rí i tí ọkunrin kan dúró níwájú rẹ̀ pẹlu idà lọ́wọ́. Joṣua lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó bi í pé, “Tiwa ni ò ń ṣe ni, tabi ti àwọn ọ̀tá wa?” Ọkunrin náà dáhùn pé, “Rárá, mo wá gẹ́gẹ́ bíi balogun àwọn ọmọ ogun OLUWA ni.” Joṣua bá dojúbolẹ̀, ó sin OLUWA, ó sì bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni o fẹ́ kí n ṣe, OLUWA mi?”