Joṣ 5:13-14

Joṣ 5:13-14 YBCV

O si ṣe, nigbati Joṣua wà leti Jeriko, o gbé oju rẹ̀ soke o si wò, si kiyesi i, ọkunrin kan duro niwaju rẹ̀ pẹlu idà fifayọ li ọwọ́ rẹ̀: Joṣua si tọ̀ ọ lọ, o si wi fun u pe, Ti wa ni iwọ nṣe, tabi ti ọtá wa? O si wipe, Bẹ̃kọ; ṣugbọn bi olori ogun OLUWA ni mo wá si nisisiyi. Joṣua si wolẹ niwaju rẹ̀, o si foribalẹ, o si wi fun pe, Kili oluwa mi ni isọ fun iranṣẹ rẹ̀?