Joṣua 5:13-14

Joṣua 5:13-14 YCB

Nígbà tí Joṣua súnmọ́ Jeriko, ó wo òkè ó sì rí ọkùnrin kan tí ó dúró ní iwájú rẹ̀ pẹ̀lú idà ní ọwọ́ rẹ̀. Joṣua sì tọ̀ ọ́ lọ, ó sì bi í pé, “Ǹjẹ́ ìwọ wà fún wa tàbí fún ọ̀tá a wa?” “Kì í ṣe fún èyíkéyìí ó fèsì, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí olórí ogun OLúWA ni mo wá nísinsin yìí.” Nígbà náà ni Joṣua sì wólẹ̀ ní iwájú u rẹ̀ ní ìbẹ̀rù, ó sì bi í léèrè, “Kí ni Olúwa ní í sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀?”