JOṢUA 5

5
1Nígbà tí gbogbo àwọn ọba ilẹ̀ Amori, tí wọ́n wà ní apá ìwọ̀ oòrùn odò Jọdani, ati gbogbo ọba àwọn ará ilẹ̀ Kenaani, tí wọ́n wà ní etí Òkun gbọ́ pé OLUWA mú kí odò Jọdani gbẹ nítorí àwọn ọmọ Israẹli, títí tí wọ́n fi rékọjá sí òdìkejì rẹ̀, àyà wọn já, ìdààmú sì bá wọn, nítorí àwọn ọmọ Israẹli.
Wọ́n Kọ Ilà Abẹ́ ní Giligali
2Nígbà náà ni OLUWA wí fún Joṣua pé, “Fi akọ òkúta ṣe abẹ, kí o sì fi kọ ilà abẹ́ lẹẹkeji fún àwọn ọmọ Israẹli.” 3Joṣua bá fi akọ òkúta ṣe abẹ, ó fi kọ ilà abẹ́ fún gbogbo ọkunrin Israẹli ní Gibeati Haaraloti. 4Ìdí tí Joṣua fi kọ ilà abẹ́ fún wọn ni pé, gbogbo àwọn ọkunrin tí wọ́n lè jagun, tí wọ́n jáde láti ilẹ̀ Ijipti, ti kú lójú ọ̀nà ninu aṣálẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti jáde láti ilẹ̀ Ijipti. 5Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo àwọn tí wọ́n jáde láti ilẹ̀ Ijipti ni wọ́n kọ ilà abẹ́, ṣugbọn gbogbo àwọn tí wọ́n bí lójú ọ̀nà ninu aṣálẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n jáde ní ilẹ̀ Ijipti kò kọ ilà. 6Nítorí pé ogoji ọdún ni àwọn ọmọ Israẹli fi ń rìn kiri láàrin aṣálẹ̀, títí tí àwọn ọkunrin tí wọ́n lè jagun, tí wọ́n jáde láti Ijipti fi parun tán, nítorí wọn kò gbọ́ ti OLUWA wọn. OLUWA sì ti búra pé, òun kò ní jẹ́ kí wọ́n rí ilẹ̀ tí òun ti búra láti fún àwọn baba wọn, ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin. 7Nítorí náà, àwọn ọmọ wọn tí OLUWA gbé dìde dípò wọn ni Joṣua kọ ilà abẹ́ fún, nítorí pé ẹnikẹ́ni kò kọ wọ́n ní ilà ní ojú ọ̀nà.#Nọm 14:28-35
8Nígbà tí àwọn eniyan náà kọ ilà abẹ́ tán, olukuluku wà ní ààyè rẹ̀ ninu àgọ́ títí egbò wọn fi jinná. 9OLUWA wí fún Joṣua pé, “Lónìí yìí ni mo mú ẹ̀gàn àwọn ará Ijipti kúrò lára yín.” Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń pe ibẹ̀ ní Giligali títí di òní olónìí.
10Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli pàgọ́ sí Giligali, wọ́n ṣe àjọ̀dún àjọ ìrékọjá ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹrinla oṣù náà, ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹriko.#Eks 12:1-13 11Òwúrọ̀ ọjọ́ keji lẹ́yìn àjọ ìrékọjá ni ìgbà kinni tí wọ́n fi ẹnu kàn ninu èso ilẹ̀ náà, wọ́n jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà ati ọkà gbígbẹ. 12Mana kò dà ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, àwọn ọmọ Israẹli kò rí i kó mọ́, lẹ́yìn tí wọ́n ti jẹ ninu èso ilẹ̀ náà. Ṣugbọn wọ́n jẹ ninu èso ilẹ̀ Kenaani ní gbogbo ọdún náà.#Eks 16:35
Joṣua ati Ẹni Tí Ó Mú Idà Lọ́wọ́
13Nígbà tí Joṣua súnmọ́ ìlú Jẹriko, ó gbé ojú sókè, ó sì rí i tí ọkunrin kan dúró níwájú rẹ̀ pẹlu idà lọ́wọ́. Joṣua lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó bi í pé, “Tiwa ni ò ń ṣe ni, tabi ti àwọn ọ̀tá wa?”
14Ọkunrin náà dáhùn pé, “Rárá, mo wá gẹ́gẹ́ bíi balogun àwọn ọmọ ogun OLUWA ni.”
Joṣua bá dojúbolẹ̀, ó sin OLUWA, ó sì bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni o fẹ́ kí n ṣe, OLUWA mi?”
15Balogun àwọn ọmọ ogun OLUWA dá Joṣua lóhùn pé, “Bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ, nítorí ibi tí o dúró sí yìí, ilẹ̀ mímọ́ ni.” Joṣua sì bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

JOṢUA 5: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀