JOṢUA 6

6
Wíwó Odi Jẹriko
1Wọ́n ti ìlẹ̀kùn odi Jẹriko ninu ati lóde, nítorí àwọn ọmọ Israẹli. Ẹnikẹ́ni kò lè jáde, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò lè wọlé. 2OLUWA sọ fún Joṣua pé, “Wò ó! Mo ti fi Jẹriko lé ọ lọ́wọ́ ati ọba wọn ati àwọn akikanju wọn. 3Ìwọ ati gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ yóo rìn yípo ìlú náà lẹ́ẹ̀kan lojumọ fún ọjọ́ mẹfa. 4Kí àwọn alufaa meje mú fèrè ogun kọ̀ọ̀kan tí wọ́n fi ìwo àgbò ṣe lọ́wọ́ níwájú Àpótí Majẹmu. Ní ọjọ́ keje ẹ óo yípo ìlú náà nígbà meje, àwọn alufaa yóo máa fọn fèrè ogun wọn. 5Nígbà tí wọ́n bá fọn fèrè ogun náà gidigidi, tí ẹ sì gbọ́ ìró rẹ̀, kí gbogbo àwọn eniyan hó yèè! Ògiri ìlú náà yóo sì wó. Kí olukuluku àwọn ọmọ ogun wọ inú ìlú náà lọ tààrà.”
6Joṣua, ọmọ Nuni, bá pe àwọn alufaa, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ gbé Àpótí Majẹmu, kí meje ninu yín sì mú fèrè ogun tí wọ́n fi ìwo àgbò ṣe lọ́wọ́ níwájú Àpótí Majẹmu OLUWA.” 7Ó sọ fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ máa tẹ̀síwájú, ẹ rìn yípo ìlú náà kí àwọn ọmọ ogun ṣáájú Àpótí Majẹmu OLUWA.”
8Gẹ́gẹ́ bí Joṣua ti pàṣẹ fún àwọn eniyan náà, àwọn alufaa meje mú fèrè ogun tí wọ́n fi ìwo àgbò ṣe lọ́wọ́ níwájú OLUWA, wọ́n ṣáájú, wọ́n ń fọn fèrè ogun wọn; àwọn tí wọ́n gbé Àpótí Majẹmu OLUWA sì tẹ̀lé wọn. 9Àwọn kan ninu àwọn ọmọ ogun ṣáájú àwọn alufaa tí wọn ń fọn fèrè ogun, àwọn kan sì tẹ̀lé Àpótí Majẹmu. Àwọn tí wọn ń fọn fèrè ogun sì ń fọn ọ́n lemọ́lemọ́. 10Joṣua pàṣẹ fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ kò gbọdọ̀ pariwo, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ gbọ́ ohùn yín. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ sọ̀rọ̀ rárá títí di ọjọ́ tí n óo sọ pé kí ẹ hó, nígbà náà ni ẹ óo tó hó.” 11Bẹ́ẹ̀ ni ó mú kí wọn gbé Àpótí Majẹmu OLUWA yí ìlú náà po lẹ́ẹ̀kan, nígbà tí ó di alẹ́, wọ́n pada sinu àgọ́ wọn, wọ́n sì sùn sibẹ.
12Joṣua dìde ní òwúrọ̀ kutukutu, àwọn alufaa gbé Àpótí Majẹmu OLUWA. 13Àwọn alufaa meje tí wọ́n mú fèrè ogun tí wọ́n fi ìwo àgbò ṣe lọ́wọ́ níwájú Àpótí Majẹmu OLUWA kọjá siwaju, wọ́n sì ń fọn fèrè ogun wọn lemọ́lemọ́. Àwọn kan ninu àwọn ọmọ ogun wà níwájú wọn, àwọn kan sì tẹ̀lé Àpótí Majẹmu OLUWA. Àwọn tí ń fọn fèrè ogun ń fọn ọ́n lemọ́lemọ́. 14Ní ọjọ́ keji, wọ́n yípo ìlú náà lẹ́ẹ̀kan, wọn sì pada sinu àgọ́ wọn. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe fún ọjọ́ mẹfa.
15Ní ọjọ́ keje, wọ́n gbéra ní òwúrọ̀ kutukutu, wọ́n yípo ìlú náà bí wọ́n ti máa ń ṣe, nígbà meje. Ọjọ́ keje yìí nìkan ṣoṣo ni wọ́n yípo rẹ̀ lẹẹmeje. 16Nígbà tí ó di ẹẹkeje, lẹ́yìn tí àwọn alufaa fọn fèrè wọn, Joṣua pàṣẹ fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ hó yèè! Nítorí OLUWA ti fi ìlú yìí le yín lọ́wọ́. 17OLUWA ti yà á sọ́tọ̀ fún ìparun, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀, àfi Rahabu, aṣẹ́wó, ati àwọn tí wọ́n wà ninu ilé pẹlu rẹ̀, ni yóo wà láàyè; nítorí òun ni ó gbé àwọn amí tí a rán pamọ́. 18Ẹ yẹra fún ohunkohun tí OLUWA ti yà sọ́tọ̀ fún ìparun, kí ẹ má baà di ẹni ègún nípa mímú ohun tí OLUWA ti yà sọ́tọ̀, kí ẹ má baà sọ àgọ́ Israẹli di ohun ìparun, kí ẹ sì kó ìyọnu bá a. 19Ṣugbọn gbogbo fadaka ati wúrà ati àwọn ohun èlò idẹ ati ti irin jẹ́ ohun ìyàsọ́tọ̀ fún OLUWA, inú ilé ìṣúra OLUWA ni a óo kó wọn sí.”
20Àwọn alufaa fọn fèrè ogun, bí àwọn eniyan ti gbọ́ ìró fèrè, gbogbo wọn hó yèè! Odi ìlú náà sì wó lulẹ̀. Gbogbo àwọn ọmọ ogun bá rọ́ wọ ààrin ìlú, wọ́n sì gba ìlú náà. 21Wọ́n run gbogbo àwọn ará ìlú náà patapata: atọkunrin, atobinrin, àtọmọdé, àtàgbà, àtakọ mààlúù, ataguntan, ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́; gbogbo wọn ni wọ́n fi idà parun.#Heb 11:30
22Joṣua sọ fún àwọn ọkunrin meji tí wọ́n lọ ṣe amí ilẹ̀ náà pé, “Ẹ wọ ilé aṣẹ́wó náà lọ, kí ẹ sì mú obinrin náà wá ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti búra fún un.” 23Àwọn ọkunrin tí wọ́n lọ ṣe amí náà bá wọlé, wọ́n mú Rahabu jáde, ati baba rẹ̀, ati ìyá rẹ̀, ati àwọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo àwọn ìbátan rẹ̀, wọ́n sì kó wọn sí ẹ̀yìn àgọ́ àwọn ọmọ Israẹli. 24Wọ́n dáná sun ìlú náà ati gbogbo nǹkan tí ó wà ninu rẹ̀, àfi fadaka ati wúrà, ati àwọn ohun èlò idẹ, ati ti irin, ni wọ́n kó lọ sinu ilé ìṣúra OLUWA. 25Ṣugbọn Joṣua dá Rahabu aṣẹ́wó sí, ati ilé baba rẹ̀, ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀, wọ́n sì ń gbé ààrin àwọn ọmọ Israẹli títí di òní yìí; nítorí pé, Rahabu ni ó gbé àwọn amí tí Joṣua rán lọ wo ìlú Jẹriko pamọ́.#Heb 11:31
26Joṣua bá gégùn-ún nígbà náà pé,#1A. Ọba 16:35
“Ẹni ìfibú OLUWA ni ẹnikẹ́ni tí ó bá dìde láti tún ìlú Jẹriko kọ́.
Àkọ́bí ẹni tí ó bá fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ yóo kú,
àbíkẹ́yìn rẹ̀ yóo kú nígbà tí ó bá gbé ìlẹ̀kùn ibodè rẹ̀ ró.”
27OLUWA wà pẹlu Joṣua, òkìkí rẹ̀ sì kàn ní gbogbo ilẹ̀ náà.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

JOṢUA 6: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa