JEREMAYA 31:15-16

JEREMAYA 31:15-16 YCE

OLUWA ní, “A gbọ́ ohùn kan ní Rama, ariwo ẹkún ẹ̀dùn ati arò ni. Rakẹli ń sọkún àwọn ọmọ rẹ̀, wọ́n ṣìpẹ̀ fún un títí, kò gbà, nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ tí kò sí mọ́. Má sọkún mọ́, nu ojú rẹ nù, nítorí o óo jẹ èrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. Àwọn ọmọ rẹ yóo pada wá láti ilẹ̀ ọ̀tá wọn.