Jer 31:15-16
Jer 31:15-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èyí ni ohun tí OLúWA wí: “A gbọ́ ohùn kan ní Rama tí ń ṣọ̀fọ̀ pẹ̀lú ẹkún kíkorò. Rakeli ń sọkún àwọn ọmọ rẹ̀; kò gbà kí wọ́n tu òun nínú, nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ kò sí mọ́.” Báyìí ni OLúWA wí: “Dá ohùn rẹ dúró nínú ẹkún àti ojú rẹ nínú omijé; nítorí a ó fi èrè sí iṣẹ́ rẹ,” ni OLúWA wí. “Wọn ó sì padà wá láti ilẹ̀ ọ̀tá.
Jer 31:15-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bayi li Oluwa wi, Ni Rama li a gbọ́ ohùnrere, ẹkún kikoro; Rakeli nsọkun fun awọn ọmọ rẹ̀, kò gbipẹ nitori awọn ọmọ rẹ̀, nitoripe nwọn kò si. Bayi li Oluwa wi; Dá ohùn rẹ duro ninu ẹkun, ati oju rẹ ninu omije: nitori iṣẹ rẹ ni ère, li Oluwa wi, nwọn o si pada wá lati ilẹ ọta.
Jer 31:15-16 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA ní, “A gbọ́ ohùn kan ní Rama, ariwo ẹkún ẹ̀dùn ati arò ni. Rakẹli ń sọkún àwọn ọmọ rẹ̀, wọ́n ṣìpẹ̀ fún un títí, kò gbà, nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ tí kò sí mọ́. Má sọkún mọ́, nu ojú rẹ nù, nítorí o óo jẹ èrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. Àwọn ọmọ rẹ yóo pada wá láti ilẹ̀ ọ̀tá wọn.