JEREMAYA 31

31
Israẹli Pada sílé
1OLUWA ní, “Àkókò ń bọ̀ tí n óo jẹ́ Ọlọrun gbogbo ìdílé Israẹli,
tí àwọn náà yóo sì jẹ́ eniyan mi.
2Àwọn tí wọ́n bọ́ lọ́wọ́ idà, rí àánú OLUWA ninu aṣálẹ̀;
nígbà tí Israẹli ń wá ìsinmi,
3OLUWA yọ sí wọn láti òkèèrè.
Ìfẹ́ àìlópin ni mo ní sí ọ,
nítorí náà n kò ní yé máa fi òtítọ́ bá ọ lò.
4N óo tún yín gbé dìde, ẹ óo sì di ọ̀tun, ẹ̀yin ọmọ Israẹli.
Ẹ óo tún fi aro lu ìlù ayọ̀, ẹ óo sì jó ijó ìdùnnú.
5Ẹ óo tún ṣe ọgbà àjàrà sórí òkè Samaria;
àwọn tí wọ́n gbin àjàrà ni yóo sì gbádùn èso orí rẹ̀.
6Nítorí pé ọjọ́ kan ń bọ̀, tí àwọn aṣọ́nà yóo pè yín láti orí òkè Efuraimu pé,
‘Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí á lọ sí òkè Sioni,
sí ọ̀dọ̀ OLUWA Ọlọrun wa.’ ”
7OLUWA ní,
“Ẹ kọ orin sókè pẹlu ìdùnnú fún Jakọbu,
kí ẹ sì hó fún olórí àwọn orílẹ̀-èdè,
ẹ kéde, ẹ kọ orin ìyìn, kí ẹ sì wí pé,
‘OLUWA ti gba àwọn eniyan rẹ̀ là
àní, àwọn eniyan Israẹli yòókù.’
8Ẹ wò ó! N óo kó wọn wá láti ilẹ̀ àríwá,
n óo kó wọn jọ láti òpin ayé.
Àwọn afọ́jú ati arọ yóo wà láàrin wọn,
ati aboyún ati àwọn tí wọn ń rọbí lọ́wọ́.
Ogunlọ́gọ̀ eniyan ni àwọn tí yóo pada wá síbí.
9Tẹkúntẹkún ni wọn yóo wá,
tàánútàánú ni n óo sì fi darí wọn pada.
N óo mú kí wọn rìn ní etí odò tí ń ṣàn,
lójú ọ̀nà tààrà, níbi tí wọn kò ti ní fẹsẹ̀ kọ;
nítorí pé baba ni mo jẹ́ fún Israẹli, àkọ́bí mi sì ni Efuraimu.”
10OLUWA ní, “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ èmi OLUWA, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè,
kí ẹ sì kéde rẹ̀ ní èbúté lókèèrè réré;
ẹ sọ pé, ‘Ẹni tí ó fọ́n Israẹli ká ni yóo kó wọn jọ,
yóo sì máa tọ́jú wọn, bí olùṣọ́-aguntan tíí tọ́jú agbo aguntan rẹ̀.’
11Nítorí OLUWA yóo ra ilé Jakọbu pada,
yóo rà wọ́n pada lọ́wọ́ ẹni tí ó lágbára jù wọ́n lọ.
12Wọn yóo wá kọrin lórí òkè Sioni,
wọn óo sì yọ̀ lórí nǹkan ọ̀pọ̀ oore tí OLUWA yóo ṣe fún wọn:
Wọ́n óo yọ̀ nítorí oore ọkà ati waini ati òróró,
ati aguntan ati ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù;
ayé wọn óo dàbí ọgbà tí à ń bomi rin, wọn kò ní dààmú mọ́.
13Àwọn ọdọmọbinrin óo máa jó ijó ayọ̀ nígbà náà,
àwọn ọdọmọkunrin ati àwọn àgbààgbà, yóo sì máa ṣe àríyá.
N óo sọ ọ̀fọ̀ wọn di ayọ̀,
n óo tù wọ́n ninu, n óo sì fún wọn ní ayọ̀ dípò ìbànújẹ́ wọn.
14N óo fún àwọn alufaa ní ọpọlọpọ oúnjẹ,
n óo sì fi oore mi tẹ́ àwọn eniyan mi lọ́rùn.
Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
Àánú OLUWA lórí Israẹli
15OLUWA ní,
“A gbọ́ ohùn kan ní Rama,
ariwo ẹkún ẹ̀dùn ati arò ni.
Rakẹli ń sọkún àwọn ọmọ rẹ̀,
wọ́n ṣìpẹ̀ fún un títí, kò gbà,
nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ tí kò sí mọ́.
16Má sọkún mọ́, nu ojú rẹ nù,
nítorí o óo jẹ èrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
Àwọn ọmọ rẹ yóo pada wá láti ilẹ̀ ọ̀tá wọn.
17Ìrètí ń bẹ fún ọ lẹ́yìn ọ̀la,
àwọn ọmọ rẹ yóo pada sí orílẹ̀-èdè wọn.
Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.#a Jẹn 35:16-19; b Mat 2:18
18“Mo gbọ́ bí Efuraimu tí ń kẹ́dùn,
ó ní: ‘O ti bá mi wí, ìbáwí sì dùn mí,
bí ọmọ mààlúù tí a kò kọ́.
Mú mi pada, kí n lè pada sí ààyè mi,
nítorí pé ìwọ ni OLUWA, Ọlọrun mi.
19Nítorí pé lẹ́yìn tí mo ṣáko lọ, mo ronupiwada;
lẹ́yìn tí o kọ́ mi lọ́gbọ́n, ń ṣe ni mo káwọ́ lérí.
Ojú tì mí, ìdààmú sì bá mi,
nítorí ìtìjú ohun tí mo ṣe nígbà èwe mi dé bá mi.’
20“Ṣé ọmọ mi ọ̀wọ́n ni Efuraimu ni?
Ṣé ọmọ mi àtàtà ni?
Nítorí bí mo tí ń sọ̀rọ̀ ibinu sí i tó, sibẹ mò ń ranti rẹ̀,
nítorí náà ọkàn rẹ̀ ń fà mí;
dájúdájú n óo ṣàánú rẹ̀.
21Ẹ ri òpó mọ́lẹ̀ lọ fún ara yín,
ẹ sàmì sí àwọn ojú ọ̀nà.
Ẹ wo òpópónà dáradára, ẹ fiyèsí ọ̀nà tí ẹ gbà lọ.
Ẹ yipada, ẹ̀yin ọmọ Israẹli,
ẹ pada sí àwọn ìlú yín wọnyi.
22Ìgbà wo ni ẹ óo ṣe iyèméjì dà, ẹ̀yin alainigbagbọ wọnyi?
Nítorí OLUWA ti dá ohun titun sórí ilẹ̀ ayé,
bíi kí obinrin máa dáàbò bo ọkunrin.”#31:22 Ìtumọ̀ gbolohun yìí farasin ní èdè Heberu.
Ọjọ́ Iwájú Àwọn Eniyan Ọlọrun Yóo Dára
23OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, “Lẹ́ẹ̀kan sí i, wọn yóo tún máa lo gbolohun yìí ní ilẹ̀ Juda ati ní àwọn ìlú rẹ̀, nígbà tí mo bá dá ire wọn pada, wọn óo máa wí pé,
‘OLUWA yóo bukun ọ, ìwọ òkè mímọ́ Jerusalẹmu,
ibùgbé olódodo.’
24Àwọn eniyan yóo máa gbé àwọn ìlú Juda ati àwọn agbègbè rẹ̀ pẹlu àwọn àgbẹ̀ ati àwọn darandaran. 25Nítorí pé n óo fún àwọn tí àárẹ̀ mú ní agbára; n óo sì tu gbogbo ọkàn tí ń kérora lára.” 26Lẹ́sẹ̀ kan náà mo tají, mo wò yíká, oorun tí mo sùn sì dùn mọ́ mi.
27OLUWA ní, “Ọjọ́ ń bọ̀ tí n óo kó àtènìyàn, àtẹranko kún ilẹ̀ Israẹli ati ilẹ̀ Juda. 28Nígbà tí àkókò bá tó, gẹ́gẹ́ bí mo tí ń ṣọ́ wọn tí mo fi fà wọ́n tu, tí mo wó wọn lulẹ̀, tí mo bì wọ́n wó, tí mo pa wọ́n run, tí mo sì mú kí ibi ó bá wọn; bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣọ́ wọn tí n óo fi kọ́ àwọn ìlú wọn tí n óo sì fìdí wọn múlẹ̀. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
29Tó bá dìgbà náà, àwọn eniyan kò ní máa wí mọ́ pé,
‘Àwọn baba ni wọ́n jẹ èso àjàrà kíkan,
àwọn ọmọ wọn ni eyín kan.’
30Kàkà bẹ́ẹ̀ ẹni tí ó bá jẹ èso àjàrà kíkan,
òun ni eyín yóo kan.
Olukuluku ni yóo kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ara rẹ̀.
31“Ọjọ́ ń bọ̀, tí ń óo bá ilé Israẹli ati ilé Juda dá majẹmu titun. 32Kì í ṣe irú majẹmu tí mo bá àwọn baba ńlá wọn dá, ní ìgbà tí mo fà wọ́n lọ́wọ́ jáde ní ilẹ̀ Ijipti, àní majẹmu mi tí wọn dà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi ni ọkọ wọn. 33Ṣugbọn majẹmu tí n óo bá ilé Israẹli dá nígbà tó bá yá nìyí: N óo fi òfin mi sí inú wọn, n óo sì kọ wọ́n sí ọkàn wọn. N óo máa jẹ́ Ọlọrun wọn, wọn yóo sì máa jẹ́ eniyan mi. 34Ẹnikẹ́ni kò ní máa kọ́ aládùúgbò rẹ̀ tabi arakunrin rẹ̀ bí a ti í mọ èmi OLUWA mọ́, gbogbo wọn ni wọn yóo mọ̀ mí ati àwọn mẹ̀kúnnù ati àwọn eniyan pataki pataki. N óo dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n, n kò sì ní ranti àìdára wọn mọ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”#Mat 26:28; Mak 14:24; Luk 22:20; 1 Kọr 11:25; 2 Kọr 3:6 #Heb 8:8-12; Heb 10:17 #Heb 10:16
35OLUWA ni ó dá oòrùn, láti máa ràn ní ọ̀sán,
tí ó fún òṣùpá ati ìràwọ̀ láṣẹ, láti tan ìmọ́lẹ̀ lálẹ́,
tí ó rú omi òkun sókè, tí ìgbì rẹ̀ ń hó yaya,
òun ni orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun.
36Òun ló sọ pé, àfi bí àwọn àṣẹ wọnyi bá yipada níwájú òun,
ni àwọn ọmọ Israẹli kò fi ní máa jẹ́ orílẹ̀-èdè títí lae.
37Àfi bí eniyan bá lè wọn ojú ọ̀run,
tí ó sì lè wádìí ìpìlẹ̀ ayé,
ni òun lè ké àwọn ọmọ Israẹli kúrò,
nítorí gbogbo ohun tí wọ́n ṣe.
38OLUWA ni, “Ẹ wò ó! Àkókò ń bọ̀ tí a óo tún Jerusalẹmu kọ́ fún mi láti ilé ìṣọ́ Hananeli títí dé Bodè Igun. 39A óo ta okùn ìwọ̀n odi ìlú títí dé òkè Garebu, ati títí dé Goa pẹlu. 40Gbogbo àfonífojì tí wọn ń da òkú ati eérú sí, ati gbogbo pápá títí dé odò Kidironi, dé ìkangun Bodè Ẹṣin, ní ìhà ìlà oòrùn, ni yóo jẹ́ ibi mímọ́ fún OLUWA. Wọn kò ní fọ́ ọ mọ́, ẹnìkan kò sì ní wó o lulẹ̀ títí laelae.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

JEREMAYA 31: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa