Mo gbọ́ ohùn kan tí ń wí pé, “Kígbe!”
Mo bá bèèrè pé,
“Igbe kí ni kí n ké?”
Ó ní, “Kígbe pé, koríko ṣá ni gbogbo eniyan,
gbogbo ẹwà sì dàbí òdòdó inú pápá.
Koríko a máa rọ, òdòdó a sì máa rẹ̀
nígbà tí OLUWA bá fẹ́ afẹ́fẹ́ lù ú.
Dájúdájú koríko ni eniyan.