N óo gbin igi kedari sinu aṣálẹ̀,
pẹlu igi akasia ati igi mitili ati igi olifi.
N óo gbin igi sipirẹsi sinu aṣálẹ̀,
n óo gbin igi firi ati pine papọ̀.
Kí àwọn eniyan lè rí i, kí wọn sì mọ̀,
kí wọ́n rò ó wò, kí òye lè yé wọn papọ̀,
pé ọwọ́ OLUWA ni ó ṣe èyí,
Ẹni Mímọ́ Israẹli ni ó ṣẹ̀dá rẹ̀.”