Kìkì Ọ̀rọ̀ Kan Tí Yíó Yí Ayé Rẹ PadàÀpẹrẹ

One Word That Will Change Your Life

Ọjọ́ 3 nínú 4

Ìlànà Kìkì Ọ̀rọ̀ Kan

Ṣètò
Láì fi gbogbo afẹfẹyẹ̀yẹ̀ ṣe, a sì fẹ́ràn pé Ọdún Tuntun lè jẹ́ àǹfààní láti pa gbogbo àṣìṣe àtẹ̀yìnwá rẹ́, ká bẹ̀rẹ̀ lọ́tun. A ní ààyè láti dín sí san'ra wa kù, láti farajìn fún ìfọkànsìn ojoojúmọ́, láti m'ókè nínú eré ìdárayá síi, láti ṣe ìgbáradì tó múná d'óko síi, láti gbàdúrà tọkàntọkàn síi, láti lo àkókò síi pẹ̀lú ẹbí wa, láti san gbogbo gbèsè táa jẹ, láti ṣe dáadáa síi nínú ẹ̀kọ́ tàbí kí á sọ̀rọ̀ Jésù fún àwọn akẹgbẹ́ àti ọ̀rẹ́ wa síi. Ṣùgbọ́n òtítọ́ ibẹ̀ nipé àwọn àkójọpọ̀ àkọọ́lẹ̀ ìpinnu wa yìí kìí sáábà wá sí ìmúṣẹ.

Ọ̀nà àbáyọ kan ni kí á tú gbogbo rẹ̀ pàlẹ̀, kí á sì ṣe àpapọ̀ rẹ̀ sí kókó ọ̀rọ̀ kan fún ọ̀dun tó ǹ bọ̀, kí á ṣeé ní ṣókí àti ní pọ́ǹbélé.

Nítorí náà, ẹjẹ́ kí ábọ́ sí ojú ọ̀gbagada kókóo Kìkì Ọ̀rọ̀ Kan yìí. Àwọn ìgbésẹ̀ tí yíó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣ'àwárí kókóo Kìkì Ọ̀rọ̀ Kan tìrẹ nìyíí. Fi s'ọ́kàn pé àwọn ìlànà yìí a máa gba àsìkò, ṣùgbọ̀n ó n'íyé lórí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Bóyá o jẹ́ eléré ìdárayá, olùkọ́ eré ìdárayá, òbí tàbí adarí okoòwò, àwọn ìgbésẹ̀ yìí lè mù àlùyọ bá ọ ní gbogbo agbọn ayé rẹ.

Ìlànà Kìkì Ọ̀rọ̀ Kan ní ìgbésẹ̀ mẹ́ta ní ṣókí – Wo inú, Wo òkè, àti kí o Wo òde.

Ìgbésẹ̀ 1 – Pèsè Ọkàn Rẹ (Wo inú) – Ibi ni wàá ti gbé ìgbésẹ̀ láti já ara rẹ gbà kúrò nínú eré àsápajúdé, ariwo àti wúruwùru. Wíwà ní ìdánìkanwà, àti ìdákẹ́rọ́rọ́ kìí ṣe iṣẹ́ kékeré, ṣùgbọ́n gbígbọ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ṣe kókó. Bí a ṣe ń gba Ọlọ́run láàyè láti yẹ ọkàn wa wò, Yíó fún wa ní òye tó yè kooro.

Ìgbésẹ̀ 2 – Ṣ'àwárí Ọ̀rọ̀ Rẹ (Wo Òkè) – Ìgbésẹ̀ yìí ń ràn wá lọ́wọ́ láti so pọ̀ mọ́ kí a sì t'ẹ́tí gbọ́ Ọlọ́run. Wíwá àayè fún àdúrà —ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tíkò lariwo lọ pẹ̀lú Ọlọ́run—ní bí ni a ó ti bẹ̀rẹ̀. Bèèrè ìbéèrè yìí lọ́wọ́ Rẹ̀: Kíni O fẹ́ẹ́ ṣe nínú mi àti nípasẹ̀ mi l'ọ́dún yìí? Ìbéèrè yìí yíó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣ'àwárí ọ̀rọ̀ tó yẹ fún ọ́. Má kàn he ọ̀rọ̀ tó dáa kan; gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni.

Ìgbésẹ̀ 3 – Gbé Ìgbé-ayé Ọ̀rọ̀ Rẹ (Wo Òde) – Ní kété tí o bá ti ṣe àwárí ọ̀rọ̀ tó yẹ fún ọ, àsìkò tó láti gbé ìgbé-ayé rẹ̀. Ọ̀rọ̀ rẹ yíó ní ìkìmí ní gbogbo agbọn ayé rẹ: l'ara, l'érò, l'ẹ́mìí, l'ọ́kàn, ní ìbájọṣepọ̀, àti pẹ̀lú nínú ètò ìsúúná. Pa kìkì ọ̀rọ̀ kan rẹ mọ́ síwájú àti ààrin gbùngbùn. Sọ kìkì ọ̀rọ̀ kan rẹ fùn ọdún fún akẹgbẹ̀ tíí múni ṣe ojúṣe ẹni àti ẹbí rẹ. Kọọ́ sílẹ̀ sínú ìwé àkọsílẹ̀ rẹ. Lẹ̀ẹ́ mọ́ ẹ̀rọ am'ómitutù rẹ. Jíròrò nípa rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹbí rẹ nídìí oúnjẹ alẹ́. Ṣe gbogbo ohun tó bá yẹ láti fi s'ọ́kàn àti kí ó máa wà l'ọ́tun síi.

A gbàdúrà pé ọdún yìí yíó jẹ́ ọdún àlùyọ fún ọ́ bí Olúwa ṣe ń mú ọ lọ sí ìpele tó kàn tí Ó sì ń lò Kìkì Ọ̀rọ̀ Kan rẹ láti mú ògo wá fún ara Rẹ̀!

Lọ
1. Kíni Ọlọ́run ń bá ọ sọ nípa kókóo Kìkì Ọ̀rọ̀ Kan rẹ báyìí?
2. Lo àsìkò tó péye láti gbàdúrà kí o sì bèèrè pé kí Ọlọ́run bá ọ sọ̀rọ̀.
3. Ṣe àtúngbéyẹ̀wò àwọn ìgbésẹ̀ mẹ́ta yìí kí o sì jẹ́ kí Ọlọ́run fi ọ̀rọ̀ tó yẹ fún ọ hàn ọ́.

Ṣiṣè tọ
Sáàmù 27:4, Sáàmù 84, Sáàmù 139

Àlékún
"Olúwa, mo gbàdúrà fún àlùyọ l'ọ́dún yìí. Lo kókóo Kìkì Ọ̀rọ̀ Kan yìí láti mú ògo wá fún ara Rẹ. Lò mí nínú gbogbo ìlànà náà. Fi òtítọ́ àti ìṣípayá hàn mí. Jọ̀wọ́ jẹ́ kí ó hàn sí mi kedere. Máa wí Olúwa nítorí ìránṣẹ́ Rẹ ńgbọ́. Ní orúkọ Jésù, àmín.”

Ọjọ́ 2Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

One Word That Will Change Your Life

KÌKÌ Ọ̀RỌ̀ KAN yíó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mú ayé rẹ rọrùn nípa f'ífojúsí KÌKÌ Ọ̀RỌ̀ KAN fún gbogbo ọdún. Ìrọ̀rùn tó wà nínú ṣíṣe àwárí ọ̀rọ̀ kan tí Ọlọ́run ní fún ọ jẹ́ kí ó jẹ́ kóríyá fún ìgbé-ayé ọ̀tọ̀. Wúruwùru àti ìdíjúpọ̀ ma ń ṣe okùnfà ìlọ́ra àti ìdálọ́wọ́kọ́, nígbàtí ìrọ̀rùn àti àfojúsùn a maá yọrí sí àṣeyọrí àti ìjágaara. Ètò-ẹ̀kọ́ ọlọ́jọ́ mẹ́rin yìí yíó fi bí a ti ń la aàrín gbùngbùn àníyàn rẹ kọjá láti ṣe àwárí ìran kìkì ọ̀rọ̀ fún gbogbo ọdún.

More

A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jon Gordon, Dan Britton àti Jimmy Page fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ kàn sí: www.getoneword.com