O. Daf 139

139
Ọlọrun Olùmọ̀ràn Ọkàn
1OLUWA, iwọ ti wadi mi, iwọ si ti mọ̀ mi.
2Iwọ mọ̀ ijoko mi ati idide mi, iwọ mọ̀ iro mi li ọ̀na jijin rére.
3Iwọ yi ipa ọ̀na mi ká ati ibulẹ mi, gbogbo ọ̀na mi si di mimọ̀ fun ọ.
4Nitori ti kò si ọ̀rọ kan li ahọn mi, kiyesi i, Oluwa, iwọ mọ̀ ọ patapata.
5Iwọ sé mi mọ lẹhin ati niwaju, iwọ si fi ọwọ rẹ le mi.
6Iru ìmọ yi ṣe ohun iyanu fun mi jù; o ga, emi kò le mọ̀ ọ.
7Nibo li emi o gbe lọ kuro lọwọ ẹmi rẹ? tabi nibo li emi o sárè kuro niwaju rẹ?
8Bi emi ba gòke lọ si ọrun, iwọ wà nibẹ: bi emi ba si tẹ́ ẹni mi ni ipò okú, kiyesi i, iwọ wà nibẹ.
9Emi iba mu iyẹ-apa owurọ, ki emi si lọ joko niha opin okun;
10Ani nibẹ na li ọwọ rẹ yio fà mi, ọwọ ọtún rẹ yio si dì mi mu.
11Bi mo ba wipe, Njẹ ki òkunkun ki o bò mi mọlẹ; ki imọlẹ ki o di oru yi mi ka.
12Nitõtọ òkunkun kì iṣu lọdọ rẹ; ṣugbọn oru tàn imọlẹ bi ọsan: ati òkunkun ati ọsan, mejeji bakanna ni fun ọ.
13Nitori iwọ li o dá ọkàn mi: iwọ li o bò mi mọlẹ ni inu iya mi.
14Emi o yìn ọ; nitori tẹ̀ru-tẹ̀ru ati tiyanu-tiyanu li a dá mi: iyanu ni iṣẹ rẹ; eyinì li ọkàn mi si mọ̀ dajudaju.
15Ẹda ara mi kò pamọ kuro lọdọ rẹ, nigbati a da mi ni ìkọkọ, ti a si nṣiṣẹ mi li àrabara niha isalẹ ilẹ aiye.
16Oju rẹ ti ri ohun ara mi ti o wà laipé: a ti ninu iwe rẹ ni a ti kọ gbogbo wọn si, li ojojumọ li a nda wọn, nigbati ọkan wọn kò ti isi.
17Ọlọrun, ìro inu rẹ ti ṣe iye-biye to fun mi, iye wọn ti pọ̀ to!
18Emi iba kà wọn, nwọn jù iyanrin lọ ni iye: nigbati mo ba jí, emi wà lọdọ rẹ sibẹ.
19Ọlọrun iba jẹ pa enia buburu nitõtọ: nitorina kuro lọdọ mi ẹnyin ọkunrin ẹ̀jẹ.
20Ẹniti nfi inu buburu sọ̀rọ si ọ, awọn ọta rẹ npè orukọ rẹ li asan!
21Oluwa, njẹ emi kò korira awọn ti o korira rẹ? njẹ inu mi kò ha si bajẹ si awọn ti o dide si ọ?
22Emi korira wọn li àkotan: emi kà wọn si ọta mi.
23Ọlọrun, wadi mi, ki o si mọ̀ aiya mi: dán mi wò, ki o si mọ̀ ìro-inu mi:
24Ki o si wò bi ipa-ọ̀na buburu kan ba wà ninu mi, ki o si fi ẹsẹ mi le ọ̀na ainipẹkun.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 139: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa