Kìkì Ọ̀rọ̀ Kan Tí Yíó Yí Ayé Rẹ PadàÀpẹrẹ

One Word That Will Change Your Life

Ọjọ́ 4 nínú 4

Gbé Ìgbé-ayé Ọ̀rọ̀ Rẹ

Ṣètò
Nígbàtí Kìkì Ọ̀rọ̀ Kan rẹ bá tọ̀ ọ́ wá, ó lè wá bíi ìhùwàsí, ìbáwí, ẹnìkan, àfojúsùn t'ẹ̀mí, ohun àwòmọ́ tàbí àbùdá. Àwọn àpẹẹrẹ ọ̀rọ̀ tí a kọ sílẹ̀ wọ̀nyí kìí ṣe ti àkọsílẹ̀ kan pàtó tí a gbọ́dọ̀ yàn láti inú wọn, bíkòṣe ìbẹ̀rẹ̀ àbá: ìfẹ́, ayọ̀, sùúrù, ìwà tútù, ìsinmi, àdúrà, ìlera, ẹ̀kọ́, ìyípadà, ìfọkànsìn, ìbáṣepọ̀ tó jinlẹ̀, ìbáwí, ìfarajì, ìgboyà, ohunrere, àwọ̀ ewé, ìrusókè, ìparí, àìlábàwọ́n, ìjólótitọ́ àti agbára.

Gbígbé ìgbé-ayé ọ̀rọ̀ rẹ yíó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ní àfojúsùn, yíó sí dènà ìdíwọ́ fún ọ. A rí ipa tí níní àfojúsùn kó fún Nehemiah nígbàtí ó ń kọ́ odi. Nínú Nehemiah 6:3, kò sọ̀kalẹ̀ kúrò nínú iṣẹ́ rẹ̀, nítorí pé ó ń ṣe ohun kan náà tí ó ti f'arajì láti ṣe—kíkọ́ odi! Ó sì ń ṣe iṣẹ́ takuntakun. Rántí pé, nígbàtí o bá gbé ìgbé-ayé ọ̀rọ̀ rẹ, ò ń ṣe iṣẹ́ takuntakun.

Kúrò nípò ìrọ̀rùn rẹ.

Ìlànà yìí ńṣe okùnfà ayọ̀, ṣùgbọ́n yíó tún mú ìpènijà lọ́wọ́. Wàá dojúkọ ìdènà tí o kò retí rẹ̀. A ó dán ọ́ wò—a s'èlérí èyí. Ṣùgbọ́n lọ́pọ̀ ìgbà a maá ń kẹ́kọ̀ọ́ tó pọ̀ jù bí a bá kúrò níbii ipò ìrọ̀rùn wa, nítorí náà dúró s'ójú òpópónà.

Ó ṣe kókó láti rántí kí o sí f'ojú sí ọ̀rọ̀ rẹ ní gbogbo ọdún. Bí ọ̀rọ̀ rẹ kò bá jẹ́ ohun àkọ́kọ́ l'ọ́kàn rẹ, yíó di ohun ìgbàgbé.

Pa kìkì ọ̀rọ̀ kan rẹ mọ́ síwájú àti ààrin gbùngbùn.

Ní gbogbo ọdún táa fi ṣe èyí jẹ èyí ò jẹ, a ti ṣ'àwárí àwọn ọ̀nà tó rọrùn tó sì l'ágbára tí a fi ń pa kìkì ọ̀rọ̀ kan ẹni mọ́ síwájú àti ààrin gbùngbùn ní gbogbo ọdún.

Àkọ́kọ́, ṣ'àfihàn ọ̀rọ̀ rẹ sí gbangba kí o baà lè máa ríi lóòrèkóòrè. Ohunkóhun tó bá wá sí àkíyèsí rẹ yíó gba àfojúsùn rẹ; ohun tó bá sì gba àfojúsùn rẹ yíó jẹ́ ṣíṣe. Ṣíṣe ètò ohun àránnilétí ṣe pàtàkì. Kọọ́ sílẹ̀ kí o sì lẹ̀ẹ́ mọ́ gbangba bíi àpótí rẹ ní ilé-ìwé, inú ọkọ̀ rẹ, lórí tábîlì rẹ tàbí ní yàrá ìpamọ̀ rẹ.

Èkejì, ṣe àjọpín ọ̀rọ̀ rẹ pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ rẹ—àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ yẹn, akẹgbẹ́ àti ẹbí tí ó ṣe pàtàkì sí ọ tí o f'ọkàn tán láìsí àníàní. A pè wọ́n ní Ẹgbẹ́ Akóniṣiṣé, nítorí wọn jẹ́ àwọn tí yíó kó ọ ṣiṣé tí wọn yíó jẹ́ kí o gbèèrú. Fún wọn ní ààyè láti béèrè ọ̀rọ̀ rẹ lọ́wọ́ rẹ.

Nígbàtí o bá ṣe àwọn ohun méjì wọ̀nyí— o ṣ'àfihàn ọ̀rọ̀ rẹ ní gbangba tí o sì ṣe àjọpín rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn—ò ń fẹsẹ̀ ìdàgbàsókè rẹ múlẹ̀. Wàá ní ìrírí ìlọsókèlọsódò, ṣùgbọ́n ara àwọn ìlànà náà ni wọ́n jẹ́. Bí o ṣe ńgbé ìgbé-ayé ọ̀rọ̀ rẹ, jẹ́ kí Ọlọ́run lo ìrọ̀rùn kókóo Kìkì Ọ̀rọ̀ Kan rẹ láti yí ìgbé-ayé ojoojúmọ́ rẹ padà.

Lọ
1. Kíni ohun kan tí o lè ṣe láti fi rántí Kìkì Ọ̀rọ̀ Kan rẹ?
2. Ṣe àkọsílẹ̀ ẹni mẹ́ta nínú àwọn tó súnmọ́ ọ pẹ́kí tí oó ṣe àjọpín ọ̀rọ̀ rẹ pẹ̀lú wọn.
3. Báwo ni o ṣe lè gbé ìgbé-ayé Kìkì Ọ̀rọ̀ Kan rẹ gègẹ́ bí ẹbí, okoòwò, ẹgbẹ́?

Ṣiṣẹ́ tọ
Nehemiah 6, Ìṣe Àpóstélì 4:16-20, Kólósè 3:17, 23

Àlékún
"Olúwa, mo gbàdúrà pé kí O ràn mí lọ́wọ́ láti gbé ìgbé-ayé ọ̀rọ̀ mi ní kíkún l'ọ́dún yìí. Gẹ́gẹ́ bíi Nehemiah, jẹ́ kí ń kọjú mọ́ àti gbé ìgbé-ayé yìí kí n sì dènà ìdíwọ́. Bí wọ́n bá sì yọjú, fún mi ní ìgboyà láti kọjû sí ohun tí O pè mí láti ṣe. Ní orúkọ Jésù, àmín."

Ṣé o fẹ́ ṣe àwòrán àlẹ̀mọ̀lé fún Kìkì Ọ̀rọ̀ Kan tìrẹ? Kàn sí: GetOneWord.com

Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

One Word That Will Change Your Life

KÌKÌ Ọ̀RỌ̀ KAN yíó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mú ayé rẹ rọrùn nípa f'ífojúsí KÌKÌ Ọ̀RỌ̀ KAN fún gbogbo ọdún. Ìrọ̀rùn tó wà nínú ṣíṣe àwárí ọ̀rọ̀ kan tí Ọlọ́run ní fún ọ jẹ́ kí ó jẹ́ kóríyá fún ìgbé-ayé ọ̀tọ̀. Wúruwùru àti ìdíjúpọ̀ ma ń ṣe okùnfà ìlọ́ra àti ìdálọ́wọ́kọ́, nígbàtí ìrọ̀rùn àti àfojúsùn a maá yọrí sí àṣeyọrí àti ìjágaara. Ètò-ẹ̀kọ́ ọlọ́jọ́ mẹ́rin yìí yíó fi bí a ti ń la aàrín gbùngbùn àníyàn rẹ kọjá láti ṣe àwárí ìran kìkì ọ̀rọ̀ fún gbogbo ọdún.

More

A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jon Gordon, Dan Britton àti Jimmy Page fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ kàn sí: www.getoneword.com